2023 Father Kukah: Ilééṣé ààrẹ fèsì sí Kukah,wọn ní ìwàásù rẹ̀ ń mú ìyapa wà láàrin àwọn ọmọ Nàìjíríà

Ileeṣẹ aarẹ lorileede Naijiria ti fesi pada si ọrọ ti Biṣọọbu ijọ Katoliiki ilu Sokoto, Matthew Hassan Kukah sọ ni itako ijọba aarẹ Buhari.

Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita ṣe wi, wọn ni Kukah lo ọrọ ajọdun Ajinde rẹ lati fi mu iyapa wa laarin awọn ọmọ Naijiria ni.

Garba Shehu to jẹ agbẹnusọ aarẹ ni ki Kukah gbaju mọ iṣẹ rẹ bi bẹẹ kọ ko darapọ mọ iṣẹ oṣelu.

Ninu alaye rẹ Garba Shehu ni ''a fi tọwọ tọwọ beere ki Kukah fi iṣejọba silẹ fawọn araalu to dibo ati oloṣelu ti wọn dibo yan ko si kọju mọ iṣẹ tiẹ''

Koda o tun fi ẹsẹ iwe mimọ kin ọrọ rẹ lyin pe ''ẹsin jẹ nkan to mọ ati pe oun to tumọ si ni ki eeyan ṣabẹwo si awọn orukan ati opo,ko si ko ara rẹ ni ijanu kuro lọr ile aye''

Bakan naa ni Garba Shehu sọ pe awọn ẹsun ti ko fẹsẹ rinlẹ ni Kukah fi n kan ijọba apapọ Naijiria.

O ni kaka ki Kukah lo asiko ọdun ajinde lati ṣe iwaasu isọkan, niṣe lo n fi n sọ ọrọ iyapa ati arinyanjinyan nipa ofin.

''awọn ẹsun to ka si ijọba lẹsẹ kan ṣe afihan iru inunibini to ni si ijọba ni''

Bẹẹ naa ni Shehutun gba Biṣọọbu Kukah lamọran [pe bo ba tiẹ fẹ bẹnu atẹ lu ijọba pẹlu ọrọ tutu lo yẹ ko fi ṣe.

O ni bi awn oniwasu tabi olori sin ba ro pe awọn ni ijọ ti yoo tẹti gbọ ọrọ wọn,''ohun ti ko da ni bi wọn baa n ko ọrọ aburu ati iyapa siwọn leti''

Igba akọkọ kọ ni yi ti Kukah ati ileeṣẹ aarẹ Naijiria yoo maa ta oko ọrọ si arawọn.

Lọpọ igba ni Father Kukah ti maa n bẹnu atẹ lu iṣejọba aarẹ Buhari paapa lori ikọlu sawọn Kristẹni ni apa ariwa Naijiria.

Kukah ti fi igba kan sọ fun ile aṣofin orileede Amẹrika pe awn janduku agbebon ati darandaran Fulani to fi mọ Boko Haram n doju le awọn ile ẹkọ ni ariwa Naijiria paapa awọn ti Kristẹni.

Ọrọ yi wa lara awọn eleyi ti ko mu ki ijọba Buhari ri gẹgẹ bi ọrẹ ti ileeṣẹ aarẹ kii si fi ọrọ bo lati ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni ti ko fran ijọba aarẹ Buhari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kókó pàtàkì márùn ùn rèé tí Bíṣọ́bù Kukah fi sọ ọ̀rọ̀ gbá ààrẹ Buhari nínú ìwàásù ọdún àjínde

Biṣọọbu ijọ Katọliki ti ilu Sokoto Matthew Hassan Kukah tun ti sọko ọrọ si ijọba aarẹ Buhari lori ailemojuto aabbo ati kikoju ajẹbanu ni Naijiria.

O fi eyi lede ninu ọrọ to sọ lori pẹpẹ lasiko ọdun ajinde eleyi to pe akọle rẹ ni 'To mend a broken nation: The Easter metaphor' .

Ninu ọrọ yi, o sọ fun aarẹ Buhari pe awọn ọmọ Naijiria ko da orileede wọn mọ mọ nitori awọn alaburu eeyan ti n ṣapata rẹ bọ lati ọjọ to ti pẹ.

Gẹgẹ bo ti ṣe ṣalaye, ipenija to n koju Naijiria kii ṣe idibo ọdun 2023 to n bọ lọna bi kii ṣe bi wọn yoo ṣe ṣọ awọn ọmọ ilẹ naa papọ ni alaafia.

Ọrọ pọ to sọ amọ awọn koko marun un kan ree ti a ri fayọ ninu rẹ:

Ajẹbanu ohun jẹgudujẹra

Labẹ akori ọrọ yi, Kukah ni bi ajẹbanu ṣe n gbooro si ni Naijiria niṣe lawọn origun igbe aye miran n dẹnukọlẹ.

Gẹgẹ bo ti ṣe wi, ''ko jẹ tuntun ka maa beere pe bawo la ṣe de ibi taa de yii. Ipenija to wa ni baa ṣe ribi jade kuro ninu ọfin taa ja si. Amọ o ṣeeṣe ka tun maa bere pe jade lọ sibo?''

O ni niṣe ni ''ọkan wa ti daru, orileede wa naa ti dẹnukọlẹ. O dabi ileewosan itọju iṣẹlẹ pajawiri ti o kun fọfọ''.

Olori ẹlẹsin, asiko to kẹẹ koju ipenija to delẹ

Nipa awọn olori ẹlẹsin Kukah ni ọrọ to ta mọ awọn naa leti aṣọ wa.

O ni asiko ti to bayi kawọn olori ijọ ẹlẹsin ṣugbaa Naijiria ki wọn koo yọ kuro ninu ewu to wa bayi.

Ati olori ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi ko si ẹnikan to yọ silẹ ''awa olori ẹsin Islaamu ati Kristẹni, a ni lati fi ododo koju ipa ti ẹsin n ko lorileede wa.''

O tẹsiwaju pe ''a gbọdo doju kọ nkan to de ba bayi to ṣe pe awọn ọgọrọ eeyan lo n fojojumọ kuro ninu ẹsin Islamu ati Kristẹni.''

O ni wọn ko le maa kọ eti ikun si ko ko ko ẹsẹ awọn ọmọ ijọ to n rin lọ si inu ainigbagbọ ati igbe aye ti ko ka Ọlọrun si.

Awọn ipenija aimọye to n koju Naijiria

Lori awọn ipenija to ni ko niye to n koju Naijiria Kukah ni eleyi to lagbara julọ kii se ti ọrọ ti idibo 2023 to n bọ lọna.

O ni ipenija bawọn ọmọ Naijiria yoo ṣe wa wa papọ ni irẹpọ jẹ eleyi to ka ni laya julọ.

Nibi lo si ti sọ bo ṣe maa n sọ tẹlẹ pe ijọba aarẹ Buhari ti mu ipinya ba awọn araalu nipa ẹsin, ẹya ati agbegbge ti wọn ti wa.

Kukah sọ pe afojusun ijọba yi nipa mimu ipinya wa laarin araalu ti sọ awọn eeyan Naijiria sinu ewu.

O pari ọrọ rẹ pe Naijiria ko ri iru ipinya bayi ri ninu akọsilẹ itan orileede naa.

Awọn janduku ajinigbe

Nibi ni Kukah ti bẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe n ṣe idarijin fawọn agbesunmọmi lorileede Naijiria.

O ni "asiko to ki a bẹrẹ si ni ronu nipa Naijiria to ju ibi tawọn ajinigbe ati janduku ti sọ ara wọn di gaba ni ilẹ wa. A ko le maa dakẹ ka si maa tan ara wa pe ikọlu to n waye yi ko lọwọ ẹsin ninu".

Kukah wa daba ọna abayọ lori ipenija yi eyi to ni ''fifi ofin mulẹ lori nkan ti iwe ofin sọ nipa jijẹ orileede ti ko faramọ ẹsin kan ju omiran lọ lo le mu ki a sọ ipo ti ẹsin yoo ko lawujọ wa.''

Kukah ni oun ko tako ẹlẹṣẹ to ba yiwa pada tabi ọdaran to ba fi iwa ọdaran silẹ ṣugbọn ṣe kii ṣe pe ọgbọn ẹwẹ ni iyipada tawọn alaburu yi lawọn yi pada jẹ?

Aarẹ Naijiria to n bọ ati iru iwa to y ko ni

Eleyi ni ṣe pẹlu awọn amuyẹ yo yẹ ki ẹni ti yoo ba jẹ aarẹ Naijiria ni ati ipenija ṣiṣe atunṣe nkan to bajẹ lara Naijiria.

O ṣe agbekalẹ awọn amuyẹ to yẹ ko wa lara ẹni to ba n gbero lati di aarẹ Naijiria.

Ninu awọn nkan to darukọ, o ni ẹni naa gbọdọ jẹ eeyan to ni ''ọkan, ẹmi ifarajin ati ẹmi ti o wa laaye' ti ko ku''

O ni ipo aarẹ Naijiria kiiṣe ipo ti o gbọdọ da lori ẹya ẹsin tabi agbegbe ibi ti ẹni naa ba ti wa.

O ni ẹni to maa jẹ aarẹ Naijiria gbọdọ jẹ ''ọlọkan, to ni ẹmi ifarajin to si gbọdọ ni gbedeke iru ijiya tawọn araalu gbọdọ jẹ labẹ rẹ''.

Kukah sọ pe Naijiria ko nilo ọrọ olugbala nbọ ti ko ni anfaani faraalu. O ni Naijiria nilo ẹni ti yoo le ṣatunto nkan to bajẹ lara Naijiria, ti yoo gbọn ebi ohun iṣẹ kuro faraalu''

Lakotan o ni ẹni ti yoo ba jẹ aarẹ gbọdọ ni ẹri ti yoo fi han pe oun le ko Naijiria yọ kuro ninu ile iwosan ti wọn sọ da yi.

O fikun pe atilẹyin ṣe pataki fun ajọ eleto idibo INEC ati awọn eronja mii fun idibo to poju owo.

O ni oun bẹnu atẹ lu awọn to n lo jagidijagan lati maa fi dunkoko mọ araalu.