You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Rotimi Akeredolu bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn tó sọ pé ó ti kú , ó ní ṣáká lara òun dá
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti sọ pe oun ko tii ku, tako iroyin ka to n lọ laarin ilu pe o ti jade laye.
Akeredolu lo fi ọrọ naa lede lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Richard Olabode.
Ninu atẹjade kan ti Olabode fi lede loju opo Facebook rẹ lo tabuku iroyin iku gomina naa, to si tun bu ẹnu atẹ lu awọn to gbe iroyin naa jade.
- Akẹ́kọ̀ọ́ Seminary tó ń kópa nínú eré "Passion for Christ" kú lórí ìtàgé, bó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyí
- Kí ló kan Ẹyin àti Ehoro nínú ìtàn àti ayẹyẹ ọdún Àjíǹde Jésú Krístì?
- Ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa òṣèré Funke Akindele lẹ́yìn ìtàgé rèé
- Ta ló ń dá ìwé àṣẹ Falana láti sójú ìdílé Adegoke dúró? Ohun táa mọ̀ rèé
- Wo àwọn ibi mẹ́rin tí ènìyàn kò le fi ẹsẹ̀ tẹ̀ láyé
- Gbogbo owó ìlú táwọn APC tó ṣe ijoba tẹ́lẹ̀ kó jẹ la ó gbà padà -Seyi Makinde
- Ẹ kò ní gbóòrùn ìgbésùnmọ̀mí mọ́ láyé ní Nàìjíríà, mo ṣèlérí - Tinubu
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Osun tẹ ọ̀dọ́ mẹ̀ta pẹ̀lú ọkàn èèyàn lágbègbè OAU
- Wo gbajúmọ̀ amúlùúdùn mẹ́fà tó kú láàrin oṣù márùn-ún
- Ọmọdé mẹ́ta jẹ Bisikíìtì tí wọn fí igbó sí ní 'Daycare' , wàhálà dé
O ni "Awọn eeyan ko jẹ ki ẹrọ ibaraẹnisọrọ mi sinmi lati nnkan bii wakati kan sẹyin."
"O si jẹ ohun iyalẹnu fun mi pe eeyan kan le wa nibikan ko si maa ro iku ro ẹnikeji rẹ."
"Gẹgẹ bii ohun ti mo sọ fun gbogbo awọn to ti pe mi ṣeyin, gomina Akeredolu ko tii ku, aaye lo wa, ko si ṣaisan kankan."
Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati ṣora fun awọn gbọyi-sọyi, ki wọn si sọra nipa bi wọn ṣe n lo oju opo ikansiraẹni lori ayelujara.
Nibo ni iroyin iku gomina Akaredolu ti jẹyọ?
Ṣaaju ni gbajumọ 'blogger' ti ọpọ mọ si Gistlover ti kọkọ jabọ pe gomina ọhun ti dagbere faye.
Ninu atẹjade ti Gistlover fi lede loju opo Instagram rẹ, o ni aisan jẹjẹrẹ 'postrate cancer'lo n ba Akeredolu finra, wọn si ti gbe lọ soke okun fun itọju.
Gistlover sọ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni gomina naa wa.
O fi kun pe iroyin to tẹ oun lọwọ fi han pe gomina naa kọkọ daku amọ o tun ji pada.
Lẹyin iroyin Gislover yii ni ọpọ awọn ololufẹ Akeredolu n woye ohun to ṣẹlẹ si gomina naa ti wọ si bẹrẹ iwadii ti wọn, amọ iroyin naa ko dun mọ awọn amugbalẹgbẹ gomina ọhun ninu.