Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìsúnmọ́ aya mi nìkan ní ìyàtọ̀ pé ń kò sí nílé

Ni Ọjọbọ ọjọ Keje osu Kẹrin ọdun 2022 ni gbajugbaja ajafẹtọẹni nilẹYoruba, Oloye Sunday Igboho ba ọpọ ọmọ Yoruba sọrọ ninu fidio kan to gbe jade.

Lati inu ile rẹ nilu Cotonou lorilẹede Benin, lo ti gbe fidio naa jade eyi ti agbẹjọro rẹ, Yomi Aliyu fi sọwọ si BBC Yoruba.

Fidio naa si ni Igboho se pẹlu atilẹyin asaaju ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ati igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Wale Adeniran.

Fido naa, ti Igboho pe ni fidio idupẹ, lo fi n se kare sawọn ọmọ Yoruba ni Naijiria ati orilẹede olominira Benin fun atilẹyin wọn.

Agbẹjọro mi ni Cotonou se ọmọluabi, gbogbo igba ti mo n binu si lo n ni ipamọra:

Nigba to bẹrẹ ọrọ idupẹ rẹ, Sunday Igboho se sadankata si agbẹjọro rẹ lorilẹede olominira Benin, Amofin Ibrahim Salami fun isẹ takuntakunto se.

Igboho ni lootọ ni oun gbena woju amofin naa lasiko kan ti oun wa lọgba ẹwọn amọ amofin naa ni ifarada pẹlu oun, ti ko si binu si oun rara.

“Ọrọ naa ko tete ye mi pe igbesẹ to gun ni lati yọ mi jade, n ko si mọ pe kii se isẹ kekere ni.

Amọ agbẹjọro Salami sisẹ takuntakun, bi mo se n binu to si, sibẹ ko binu pada, mo si dupẹ pupọ fun ifarada ati atilẹyin rẹ fun mi.”

Igboho ni eeyan ko le wa, ko ma ja, ti oun si fa ibinu yọ nigba ti oun ko ri agbẹjọro naa.

O ni amọ Ọlọrun se amofin Salami ni onisuuru, to si pada wa ba oun bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan ti sin ni gbẹrẹ ipakọ pe ko ma da oun lohun.

O wa gbadura fun agbẹjọro naa pe ẹmi rẹ yoo gun, ti yoo si maa se aseyọri ninu gbogbo idawọle rẹ.

Akọni nla ni aarẹ ilẹ Benin, irọ ni pe o gba ọwọ lọwọ Buhari tabi dalẹ Yoruba:

Nigba to n sọ iriri rẹ lasiko to wa ninu ọgba ẹwọn lorilẹede Cotonou, Sunday Igboho ni titi lai ni oun yoo maa dupẹ lọwọ aarẹ orilẹede olominira Benin, Patrice Talon.

O ni aarẹ Talon ko jẹ ki oun mọ ala pe oun ko si ninu ile oun lasiko ti oun wa lọgba ẹwọn, nitori oun gbogbo lo fi tẹ oun lọrun.

“Aarẹ daadaa ni Talon, ọkunrin takuntakun ni. Oniruuru ahesọ ọrọ lo n ja rainrain nigba ti wọn mu mi sọgba ẹwọn.

Ẹlomiran ni Aarẹ Talon ti gba owo lọwọ aarẹ Buhari ni Naijiria, o si ti dalẹ Yoruba, amọ gbogbo rẹ, irọ nla ni.

Ẹ wo mi wo, se mo jọ ẹni to lọ si ẹwọn, koko ni ara mi le nitori Talon tọju mi gidigidi.

Aile maa ba iyawo mi sun nikan ni iyatọ pe n ko si ninu ile mi nibi ti mo gbadun de.

Koda, o tun fun mi ni awọn dokita ti yoo maa se itọju mi, ti mo ba ni ori n fọ mi lasan, wọn ti de lati wa fun mi ni ohun gbogbo ti mo fẹ”

Bakan naa ni Igboho salaye pe gbogbo jijẹ mimu oun lọgba ẹwọn naa, irọrun lo ba de, aarẹ Talon ko si fi ohunkohun ni oun lara.

O wa salaye pe ti orilẹede Naijiria ba ri bi orilẹede Benin ni, oun ko ni jade sita pe oun n jija gbara fun ominira ilẹ Yoruba.

Ko ko ko ni ara ọta mi le, ẹyin ọmọ Yoruba, mo n bọ nile laipẹ:

Sunday Igboho wa tẹsiwaju ninu fidio naa pe ko si nkankan to se oun ninu ọgba ẹwọn,

O ni irọ ni ahesọ ọrọ pe wọn yin oun nibọn ni ẹsẹ, tabi pe oun rọ lapa, o ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

O wa dupẹ lọwọ awọn to duro ti lasiko to wa lọgba ẹwọn, ati awọn eeyan to se ilede lẹyin rẹ.

Lara wọn ni Ọjọgbọn Banji Akintoye ati igbakeji rẹ, Wale Adediran, awọn ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi.

Bakan ni Igboho wa dupẹ lọwọ iyawo rẹ Ropo, fun aduroti rẹ, to si ni aya rere ati alalubarika ni.

Ta ni Sunday Igboho, bawo ni irinajo rẹ sọgba ẹwọn se bẹrẹ?

Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho lo jẹ ajijagbara ati ajafẹtọẹni nilẹ Yoruba.

Ẹni ọdun mọkandinlaadọta nii se, to si jẹ gbajumọ onisowo to n ta ọkọ nilu Ibadan.

Igboho wa lara awọn asiwaju ẹgbẹ to n beere fun idasilẹ orilẹede fun ẹya Yoruba lati ipasẹ ijijagbara fun Yoruba Nation.

Koda, o ti gbe ipolongo fun idasilẹ Yoruba Nation naa yika gbogbo awọn olu ilu ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba.

Amọ lọjọ Kinni osu Keje ọdun 2021, ni deede aago kan oru ni awọn osisẹ ologun ọtẹlẹmuyẹ DSS kọlu ile Igboho to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan.

Ikọlu naa lagbara to bẹẹ ti ẹmi eeyan meji sọnu, wọn ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ, nigba ti wọn si fi ṣikun ofin mu awọn mejila miran.

Amọ Igboho ri ọna sa kuro ninu ile naa, ti ọwọ awọn DSS ko si tẹ ẹ.

Asiko yii lo gbiyanju lati lọ silẹ Germany fun itọju ni ọjọ kẹrindinlọgbọn osu Keje ọdun 2021 naa.

Igboho si gba papakọ ofurufu ilu Cotonou lọ, lorilẹede olominira Benin lati rekọja silẹ Germany amọ ọwọ awọn agbofinro tẹ oun ati aya rẹ, Ropo, ti wọn si fi si ahamọ kan nilu Cotonou

O yọju sile ẹjọ amọ wọn ko ri ẹsun kankan fi kan, ko to wa gba idande kuro lọgba ẹwọn, lọ sile rẹ ni Cotonou lọjọ Keje osu Kẹta ọdun 2022.