Abuja- Kaduna Train Attack: Iye ìgbà tí Olusegun Obasanjo ti fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti n fi ero wọn lede lori gbolohun ti aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Olusegun Obasanjọ sọ lori iṣẹlẹ ọkọ oju irin ti awọn agbebọn ṣekọlu si to si gbẹmi eniyan mẹjọ, nigba ti mejidinlaadọjọ di awati.

Ohun ti aarẹ Buhari sọ si iṣẹlẹ naa ni pe aarẹ Buhari ati awọn oṣiṣẹ ijọba ko mọ ohun ti wọn le ṣe mọ lori eto aabo Naijiria.

O ni o ti su wọn bakan naa ni o ti rẹ wọn, ati wipe ọwọ awọn ologun ko ka awọn agbebọn ati awọn agbesunmọmi yii mọ.

Bakan naa lo fikun pe ti wọn ko ba ṣọra ṣe o ṣeeṣe ki awọn iṣẹlẹ awọn agbebọn yii ma jẹ ki idibo gbogboogbo waye ni ọdun to n bọ.

Amọ igba akọkọ kọ ni yii ti aarẹ Buhari yoo ma fi ero rẹ han lori igbesẹ ijọba Buhari si eto aabo to dẹnukọlẹ ati awọn ohun ti ko tẹ lọrun lori iṣejọba rẹ.

2018- Buhari kuro lori oye nigba to si yẹ o

Ọdun 2018 ni Aarẹ tẹlẹri, Oluṣẹgun Obasanjọ ti kesi aarẹ Buhari lati maṣe dije dupo saa keji ni ọdun 2019.

Obasanjọ ni Buhari ti kuna patapata gẹgẹ bi adari lorilẹede Naijiria nitori naa ko fi ipo silẹ.

Bakan naa lo parọwa si Buhari lati fi ipo silẹ ko si darapọ mọ awọn adari ni orilẹede Naijiria tẹlẹri ti wọn ti ni imọ oye lati tukọ bo ṣe dara to.

2020 - Orilẹede Naijiria ti dojuru patapata

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo fesi ni ọdun 2020 lasiko ti Obasanjo ni orilẹede Naijiria ti n lọ si oko igbagbẹ.

Obasanjọ ni rudurudu lo n ṣẹlẹ ni ijọba aarẹ Buhari to fi mọ ogun ẹlẹyamẹya.

Amọ ijọba Buhari ni Obasanjo ko duro ni ipo agba to yẹ ko duro si ati wi pe ọrọ to n da ija silẹ lo n sọ.

2021 - Aarẹ Buhari ti ṣe iwọn to le ṣe, ẹ fi iyoku silẹ

Ọdun to kọja ni Buhari kesi awọn Naijiria lati ma ṣe ro pe Buhari ni olugbala wọn nitori ko si oun to le ṣe mọ.

Obasanjo ni Buhari ti ṣe iwọn to le ṣe ki awọn ọmọ Naijiria kuro lori igbekele ninu ijọba rẹ.

O ni oun to ku fun wọn ni lati ma a ro bi ohun gbogbo yoo se dara lẹyin ti aarẹ Buhari ba kuro lori ipo.

2022: Agbara Aarẹ Buhari ko ka iṣẹlẹ ikọlu ojoojumọ yii mọ

Obasanjọ ni eto aabo lorilẹede Naijiria to dẹnukọlẹ yii ti kọja keremi to si fi imọran ranṣẹ si Aarẹ Buhari.

Obasanjo ni ki Buhari kan si awọn eekan ni awujo lati da iji ikọlu olojojumọ yii duro.

O fikun pe agbara Buhari ko ka ọrọ naa mọ, to si ko pe fun iranwọ.

Amọ ijọba Naijiria ti fesi pe ko si ohun to jọ bẹẹ, nitori ikọ ologun ni Naijiria n ṣe iwọn ti wọn le ṣe.

Iṣẹlẹ ọkọ oju irin ti awọn agbebọn ṣekọlu si naa gbẹmi eniyan mẹjọ, ti mejidinlaadọjọ si di awati.