IBEDC Okeho: Bí ẹ kò bá fún wa ní iná, a kò ní ṣí ọ́fíìsì yín - Olùgbé Okeho

Àwọn ará ìlú Okeho ní ìjọba ìbílẹ̀ Kajọla, ìpínlẹ̀ Oyo ti ti ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná (IBEDC) tó wà nínú ìlú náà.

Àwọn ará ìlú tí inú ń bí náà gbé ilé iṣẹ́ náà tì pa nítorí pé wọn kò ní iná rárá fún ọjọ́ mọ́kànlá.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní àwọn ọ̀dọ̀ ìlú náà kó ara wọn jọ láti lọ ti ilé iṣẹ́ náà lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti foríkorí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Láti ọjọ́ mọ́kànlá sẹ́yìn ni a ti ní iná kẹ́yìn, èyí ló sì jẹ́ kí a pinnu láti lọ ti iléeṣẹ́ IBEDC tó wà fún iná pínpín ní ìlú wa pa".

Wọ́n ní iléeṣẹ́ náà yóò wà ní títì pa títí àwọn yóò fi yí ìpinu àwọn padà, tí àwọn kò sì tíì mọ ìgbà tí yóò jẹ́.

Àkọ́lé tó wa lára ìwé tí wọ́n lẹ̀ mọ́ iléeṣẹ́ IBEDC fi hàn pé ọjọ́ mẹ́fa ni ìlú náà fi ní iná nínú oṣù kẹta yìí.

Kìí ṣe ẹjọ́ wa pé kò síná - IBEDC

Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn kàn sí olórí ẹ̀ka ìròyìn iléeṣẹ́ IBEDC ìlú náà, Busola Tunwase ní kìí ṣe ẹjọ́ àwọn pé kò sí iná nínú ìlú náà.

Tunwase ni ohun tí wọ́n bá fún àwọn ni àwọn yóò pín àti pé kò sí iná nílẹ̀ báyìí.

Ó ní kìí ṣe ọ̀rọ̀ Okeho nìkan bíkòṣe ọ̀rọ̀ gbogbo Nàìjíríà lápapọ̀.

Ó fi kun pé àwọn ti lọ bá àwọn ará ìlú náà tí àwọn ti lọ bẹ̀ wọ́n.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní àwọn ti ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún wọn.