Oyo APC Crisis: Wàhálà awuyewuye ẹgbẹ́ òṣèlú APC gba ọnà míì yọ pẹlú ìyànsípò alága igun ìkejì

Ọrọ awọn ti yoo ṣakoso ẹgbẹ oṣelu PAC ni ipinlẹ Oyo tun ti gbọna mi yọ pẹlu iburasipo fun alaga igun ẹgbẹ naa kan lọjọ Ẹti.

Alhaji Abu Gbadamosi la gbọ pe wọn ṣe eto iburawọle sipo fun ni ile igbafẹ Trans Wonderland taa mọ si Amusement Park ni Bodija Ibadan.

Amofin Kehinde Owoade la gbọ pe o ṣe ibura sipo fun Gbadamosi.

Bi a ko ba gbagbe,fakinfa ti n waye lori iṣakoso ẹgbẹ naa ni Oyo ti awọn alẹnulọrọ kan si ti fapajanu lori iyansipo Isaac Omodewu gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ.

Ohun tawọn to tako iyansipo rẹ ṣe lalaye ni pe eto idibo to gbe wọle ni kọnun kọhọ ninu ati pe igbimọ amu'sẹya ti kọ eto idibo yi.

Ninu awọn to peju sibi iburasipo alaga igun yi ni Sẹnẹtọ Ayo Adeseun.

Lalẹ ana iroyin tẹwa lọwọ pe awọn ọlọpaa gba akoso olu ile ẹgbẹ to wa ni Oke0-Ado ni Ibadan.

A ko ribi fidi ohun to mu ki awọn ọlọpaa gba akoso ayika olu ile ẹgbẹ naa ṣugbọn eleyi lo mu ki awọn igun to ṣe iburawọle yi gbe lọ si Amusement Park.

Ninu awọn eekan ẹgbẹ APC to ti tako igbimọ adari ẹgbẹ labẹ akoso Omodewu la ti ri Minisita feto ọdọ ni Naijiria Sunday Dare,Minisita feto ibaraẹnisọrọ nigba kan ri, Adebayo Shittu ati Sẹnẹtọ Olufemi Lanlehin.

Awọn miran ni Adebayo Adelabu to jẹ oludije ipo Gomina labẹ asia APC ninu idibo Gomina to kọja.

Ohun ti iyansipo yi tunmọ si bayi ni pe aawọ to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo tunbọ n ṣe akoba fun igbiyanju ẹgbẹ naa lati gba ijọba pada lọwọ PDP to wa lori oye.

Bi nkan ti ṣe nlọ yi, ti APC ko ba fẹnu ko, yoo ṣoro fun wọn lati ja agbara gba lọwọ PDP labẹ idari Gomina Seyi Makinde.

Irufẹ aigbọraẹniye ninu ẹgbẹ yi lati igba aye Gomina tẹlẹ Abiola Ajimobi lo mu ki APC fidirẹmi lọwọ PDP ninu idibo Gomina ọdun 2019.