You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oyo APC crisis: Ìwà màdàrú àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni kò jẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC tòrò ní ìpínlẹ̀ Oyo - Akintola
Láti bí ọjọ́ mélo kàn sẹ́yin ni gbọ́misí-omi-òtó tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progessive Congress (APC) ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Sùgbọ́n àrà tuntun ni ó tún gbéyọ ni ọjọ́ Sátidé ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan, ọdun 2021, nígbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ APC ṣe ìpàdé ẹgbẹ́ ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílùú Ibadan.
Ìkan wáyé ni ìjọba ìbílẹ̀ Ibadan North, ni Oke -Apon, lágbègbè Yemetu, nígbà tí òmíràn wáyé ni Emmanuel College ni Samonda, Ibadan.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn agba ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn ti wọn n mura lati gbe apoti ibo gan lo n da ẹgbẹ ọhun ru.
Igbakeji alaga ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo tẹlẹ, amofin Adeniyi Akintola lo sọ bẹẹ fun fun BBC Yoruba.
O ṣalaye pe ipade naa to waye ni ojuko ọtọọto ko le ni ipa to buru pupọ lara ẹgbẹ naa nitori ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ lasan ni, irufẹ ija bẹẹ si san ju ija laarin ọmọ ẹgbẹ awọn ati ọmọ ẹgbẹ mii lọ.
"Ibi ti ẹgbẹ ba fẹnuko si lo yẹ ki ipade naa ti waye, yala nile ẹkọ ijọba ni tabi ti aladani, kii ṣe ibi to ba wu wọn."
O ni "Awọn ti wọn lọ ṣe ipade nibi ti ẹgbẹ ko fọwọ si ni wọn lu ofin ẹgbẹ, nitori awọn to ba pe ipade ni yoo sọ ojuko ti ipade ọhun yoo ti waye, kii ṣe awọn ti wọn pe fun ipade."
O sọ siwaju si pe pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni ko niṣẹ lọwọ, oṣelu si ni wọn fi n ṣe iṣẹ oojọ wọn, idi ree ti wọn fi n da ẹgbẹ ru nitori ọna atijẹ kan ṣoṣo kan ti wọn ni niyẹn.
Ni ti ọna ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo gba lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP to n ṣejọba lọwọ nipinlẹ Oyo, Akintola sọ pe "Iyẹn wa lọwọ Ọlọrun Ọba, o tun wa lọwọ awa ọmọ ẹgbẹ naa."
"Awa ti a fẹ gbe apoti ibo gan ni a n da ẹgbẹ ru, kii ṣe awọn to n tẹle wa lẹyin."
Bo tilẹ jẹ pe Akintola ti gbe apoti ibo tẹlẹ, o si n mura lati gbe apoti lẹẹkan si, o ni awọn aṣaaju ẹgbẹ kan n lo ipo, eeyan mimọ, ọrọ ẹlẹyamẹya ati owo lati da ẹgbẹ oṣelu APC naa ru nipinlẹ Oyo.
Alága ẹgbẹ́ APC méjì ló yọjú ní ìpínlẹ̀ Oyo lọ́jọ́ Sátidé
Láti bí ọjọ́ mélo kàn sẹ́yin ni gbọ́misí-omi-òtó tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progessive Congress (APC) ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Sùgbọ́n àrà tuntun ni ó tún gbéyọ ni ọjọ́ Sátidé ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan ,ọdun 2021, nígbà tí àwọn ọmọ APC ṣe ìpàdé ẹgbẹ́ ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílùú Ibadan.
Ìkan wáyé ni ìjọba ìbílẹ̀ Ibadan North, ni Oke -Apon lágbègbè Yemetu nígbà tí òmíràn wáyé ni Emmanuel College ni Samonda, Ibadan.
Àwọn adarí àpapọ̀ ẹgbẹ́ ló ṣe àmújútó, ètò bí ètò náà ṣe lọ ni ti èyí tó wáyé ni òkè Apon, sùgbọ́n ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ló mójú tó ti èyí tó wáyé ni Samonda ní ìlú Ibadan.
Lẹ́yìn tí ètò parí ní ti Oke Apon Tirimisiyu Saka ni wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ̀ bi alága ẹgbẹ́ fún ìjọba ìbílẹ̀ náà
Bákan náà ni wọ́n ya àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ mẹ́rìndílọ́gbọ̀n mííràn fún ìjọba ìbílẹ̀ náà.
Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ko dárúkọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó jáwé olúborí nínú ìdìbò tó wáyé ni Emmanuel College ni Samonda.
Agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà ni Ibadan Abdulazeez Olatunde fidi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀, sùgbọ́n ó ṣàlàyé pé, ìsòro náà kò pẹ́ to fi yanjú.
Ó ní àwọn kàn ń retí kí olúkúlùkù ṣe nǹkan to ba wù wọ́n láti ọkàn wọn ni, sùgban gbogbo rẹ̀ yóò ní ìyànjú