Lagos fuel souvenir: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ṣe ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti ti gbọngan igbalejo ayẹyẹ Havillah event center to wa lagbegbe Oniru nipinlẹ Eko pa.

Gbọngan igbalejo ayẹyẹ Havillah event center yii layẹyẹ owanbẹ ti wọn ti pin epo bentiro gẹgẹbi ẹbun amurele ti fidio rẹ lu ayelujara pa ti waye.

Lọsan ọjọ Abamẹta lawọn oṣiṣẹ ajọ idaabobo araalu nipinlẹ Eko, Lagos state Safety Commission atawọn agbofinro ikọ kogberegbe Rapid Respnse Squad nipinlẹ Eko lọ ti ibudo igbalejo ayẹyẹ naa pa fun titapa si ofin to de abo araalu.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Ijọba ipinlẹ Eko ti kọkọ ṣeleri pe awọn yoo ṣewadii awọn to wa nidi ayẹyẹ naa eyi ti wọn ni o lee mu ọpọlọpọ ofo ẹmi ati dukia waye.

Bakan naa ni iroyin tun sọ pe kọmiṣọna ọlpaa ni ipinlẹ Eko ti paṣẹ ki awọn ọlọpaa lọ awọn to ṣe ayẹyẹ naa kan, ki wn si fi panpẹ ofin mu wọn

Ta lo ṣe ayẹyẹ yii gan?

Arabinrin to ṣe pati owanbẹ naa, Erelu Ọkin ti jade sita lati tọrọ aforiji lori iṣẹlẹ naa.

Erelu Ọkin gbe atẹjade aforiiji rẹ ranṣẹ sori oju opo instagram rẹ, pẹlu orukọ 'lapearlnyc'

O ni asiko ailarojinlẹ oun ni iṣẹlẹ naa ati pe ohun ko gbero ati ṣe ijamba fun ẹnikẹni tabi awujọ.

"Erongba mi ni lati fi imore han fawọn alejo mi fun fifarahan lainaani bi ilu ṣe kan gogo si lasiko yii"

Ìjọba Eko ní òun yóò ṣe ìwádìí lórí ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko

Ni opin ọsẹ yii lawn fidio kan lu sori ayelujara nibi ti awọn alakoso apejẹ kan ti n fi epo bẹntiro ṣe ẹbun amurele fun awọn eeyan to wa sibi ayẹyẹ o wanbẹ wọn.

Kii ṣe iroyin mọ pe ọwọngogo epo bẹntiro ti sọ ọrọ aje ati igbayegbadun awn ọmọ Naijiria di nnkan miran bayii eleyii to si mu ki igbesẹ naa o mu ki ọpọ awọn to wo o maa ṣe haa hin.

Ko tii si ẹni lee sọ pato awọn to n ṣe ayẹyẹ naa ṣugbọn lara awọn ohun to han nibẹ ni pe gbajumọ olorin Fuji ni, Sule Alao Malaika lo wa loju agbo to n kọrin ninu ọkan lara awọn fidio naa to lu igboro kan.

Iwa to lewu gidigidi to si lee ja si adanu ọpọlọpọ ẹmi ni - Ijọba ipinlẹ Eko

Nibayii, ijọba ipinlẹ Eko ti ni oun yoo gbe igbesẹ iwadii lori ọrọ naa.

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna feto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ fi sita, ijọba ipinlẹ Eko ni "ko si aniani pe iwa to lee fa adanu nla leyi j, to si tun lee jasi ofo ẹmi ati dukia."

O ni ajọ idaabo bolu nipinlẹ Eko, iyẹn Lagos state safety commission ti bẹrẹ iwadii lori rẹ; ti wọn yoo si rii daju pe gbogbo awọn ti aje iwa aitọ naa ba ṣi mọ lori finmu ko ata ofin.

Ijọba ipinlẹ Eko tun tẹ siwaju lati sọ pe, gbogbo eto to yẹfun didaabo bo awọn eeyan ipinlẹ Eko ni iṣejọba gomina Babajide Sanwo-Olu n gbe, pẹlu amọran pe ki awọn eeyan yago fun iwa to lee fa pipadanu ẹmi ati dukia.

Ki lohun tawọn ọmọ Naijiria sọ nibẹ

Iṣẹlẹ naa jẹ eyi to si mu ki awọn ọmọ Naijiria lori ayelujara o maa pariwo pe ajalu nla lo n duro lati ṣẹlẹ lagbegbe naa bi ina kan ba lọ ṣeṣi sọ laarin wọn nibẹ.