Olubadan enthronement: Àwọn àgbà oyè Ibadan fẹnukò láti gbé ẹjọ́ kúrò nílé ẹjọ́

Awọn ọmọ igbimọ oloye agba Ibadan ti gba lati gbe ẹjọ ti wọn pe lori wahala to waye nigba aye Olubadan ana lori ipo awọn oloye to gbade lọwọ gomina tẹlẹ, Abiọla Ajimọbi.

Awọn agba oye ilẹ Ibadan naa gbe igbesẹ ọhun nibi ipade wọn to waye laafin Olubadan to wa lagbegbe Ọja'aba nilu Ibadan.

Ipinnu wọn tuntun yii ni ọpọ n woye pe yoo tubọ yẹna fun yiyan Olubadan tuntun lẹyin ti wọn ti kọkọ sọ ọ ṣaaju pe Ọtun Olubadan, Oloye Lekan Balogun ni Oye naa sun kan.

Ọtun Balogun ilẹ Ibadan, Agba Oye Tajudeen Ajibọla ṣalaye fawọn Oniroyin lẹyin ipade naa pe adehun ti wa laarin awọn ati gomina ipinlẹ Ọyọ lati gbe ẹjọ naa kuro ni ile ẹjọ.

O ni ilana gbigbe ẹjọ naa kuro niwaju ile ẹjọ ti bẹrẹ.

Ile ẹjọ ti kọkọ sun igbẹjọ lori ẹjọ naa siwaju tẹlẹ di ọjọ kinni oṣu keji ọdun 2022.