You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akeredolu: N2.5bn owó Yorùba tó ń bọ́ sókè ọya lójúmọ́ lórí ríra màálù kò mọ́gbọ́n dání
Ẹgbẹ to n pe fun ominira ilẹ Yoruba, Ilana ọmọ Oodua ti kede pe oun fara mọ̀ ohun ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu sọ.Gomina Akeredolu lo ti kede saaju pe ki awọn ọmọ Yoruba maa jẹ ẹran adiẹ a n sin labẹle ati ogunfe to n se ara loore dipo ẹran maalu, to n se akoba fun agọ ara.Nigba to n sọ ero rẹ lori imọran Akeredolu yii, Ilana Omo Oodua, ti Ọjọgbọn Banji Akintoye ko sodi ni oun fara mọ ero gomina naa.
Ẹgbẹ ajijagbara naa ni ootọ ọrọ ni ohun ti Akeredolu sọ pe biliọnu meji ati aabọ lo n kuro ninu ọrọ aje Yoruba lojoojumọ lati fi mu agbelarugẹ ba apa ariwa Naijiria eyi ti ko mu ọgbọn dani.O wa gba awọn ọmọ Yoruba nimọran lati tẹwọgba ilana 'Gbin ohun to ba fẹ́ jẹ́, ko to di pe orilẹede Yoruba Nation dohun. Ilana ẹgbẹ ọmọ Oodua sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan to fisita fawọn akọroyin.
Atẹjade naa wa kan saara si gomina Akeredolu lori ikede rẹ ati igbesẹ akin to gbe nipa jijẹ olootọ silẹ Yoruba.Ilana ọmọ Oodua wa rọ awọn ọmọ Kaarọ oojiire lati se atilẹyin fun imọran naa, ki wọn si mu lo pẹlu.