Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji: Ooni Ile Ife fẹ́ gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara rẹ̀, àlàyé tó ṣe nípa rẹ̀ nìyí

Bi ọpọ ba ri kabiyesi Ọọni ile Ifẹ, ko fẹrẹ si ẹni to lee roo kan Adeyẹye Ogunwusi, Arole Oodua pe Ọbalaye yii ti figbakan ri gbero ati gba ẹmi ara rẹ.

Ki o to de ori oye, Adeyẹye kii se talaka bẹẹni kii ṣe ọlẹ, oniṣowo to gbajumọ to si lamilaaka ni.

Nitori naa nigba to mu ẹnu le ọrọ ni gbọngan aṣa MUSON Center nilu Eko, pe awọn asiko kan wa ti ilẹ poyi fun wọn to bẹẹ ti awọn fi pinnu lọkan awọn pe iku ya ju ẹsin lọ.

Ọọni Ile Ifẹ, lọfin Adimula Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji ṣalaye pe aye ti su oun ri debi pe oun gbiyanju ati gbẹmi ara oun ṣugbọn ti oun ni lati yiri rẹ wo lẹyin ti oun gbọ awọn orin agbọronu kan.

Ọọni ile Ifẹ Adeyẹye Ogunwusi ni orin jẹ ọkan pataki lara awọn opo ti Eleduwa fi gbe iṣẹda eniyan ro.

Ọọni Ogunwusi sọ eyi di mimọ lasiko to fi n sọrọ nibi iṣide ayẹyẹ orin kan nilu Eko.

Ki lo ṣẹlẹ si Ọọni Adeyẹye Ogunwusi to fi fẹ gbẹmi ara rẹ?

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi Ọọni ile Ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi ni oun ti di odu nla loko akọleta lagbaye lati igba ti oun ti wa ni ọdọ ti awọn eekan gbogbo lawujọ si ti n ba oun duna dura ni gbogbo igba ti aje si ti n bu igba jẹ.

Kabiyesi Ogunwusi ni iṣẹlẹ kan lo ṣẹlẹ ti gbogbo nnkan fi dabi eyi to yipo fun oun debi pe oun wo o pe ọna abayọ kan ṣoṣo to ku fun oun ni lati roo pe ki oun gba ọna ọrun lọ nitori o san ki oun ku.

"Mo gba owooya loonu biliọnu mẹjọ naira kan ni nnkan bii ọdun mejila sẹyin lati kọ ile alaja gogoro kan ti mo ni lati wo palẹ funra mi nigba ti mo kọ ile naa de aja kẹwaa, gbogbo owo ba wọmi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

  • Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
  • Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
  • Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
  • Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa 'Ajala Travels'?
  • Wòlíì Kasali ní Dolapo Awosika kò lé ìyàwó òun jáde
  • 'Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ'
  • Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?

Ile aye yi pada ni obiripo fun mi, ọna abayọ kan ṣoṣo ti mo ri funra mi ni lati gba ẹmi ara mi lẹyin eyi.

Ṣugbọn nigba ti mo gbọ awọn orin agbọronujinlẹ kan lọlọkan-o-jọkan, mo nilo lati tun ero mi pa ki n si ranti ọrọ awọn agba pe 'bi ẹmi ba wa ireti n bẹ"

Ọọniriṣa wa ṣalaye siwaju sii pe lati igba yii wa loun ti maa n lo orin gẹgẹbii ohun elo imọkanle lasiko yoowu ti oun ba ti n la awọn ipenija kọja.

Pataki orin lasiko ipennija gẹgẹ bi Ọọni Ile Ifẹ ṣe sọ

Alaye Ọọni ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji lori ọrọ orin lẹyin o rẹyin ni pe oun gẹgẹ bi ẹnikan ti mu orin kikọ ati gbigbọ gẹgẹ bi ọna abayọ si idojukọ oun gbogbo.

Bakan naa lo ṣeleri pe oun ti pinnu lọkan oun lati igba naa lati gbin idokowo to yẹ sori orin ati iṣẹ ọna lati lee ro awọn ọdọ atawọn to ku diẹ kaato fun lawujọ lagbara lati rọwọ họri.