Electoral Act Bill: Àwọn aṣòfin Naijiria buwọ́lu fífi èsì ìdìbò ránṣẹ lórí ayélujára

Apapọ ile asofin Naijiria ti buwọ́lù àṣẹ fun àjọ eleto idibo INEC lati le fi esi idibo ránṣẹ gba ori ayelujara.

Wọn fòntẹ̀ lù lẹyìn tí wọn gbà abajade igbimọ iwadii lori ọrọ yi lọjọ Ìṣẹgun.

Ohun tí eyi tumọ sí ni pe awon aṣòfin ti pari isẹ lori àtúnṣe ofin tó dé eto idibo ni Naijiria.

Ohun tó kù bayi ni pé kí wọn fi ranṣẹ sí aarẹ Muhammadu Buhari ko buwọ́lù.

Ariwo aráàlú to pọ loṣu Kẹwàá lori pe ki wọn jẹ kí INEC máa fi esi idibo ránṣẹ lori ayelujara leyin tawon eeyan ni wọn kò gbọdọ f'asẹ sí aba Electoral Act lo mu kawon aṣofin gbe igbesẹ yi.

Awijare awọn asofin lori ọrọ yi ni pe INEC ko le gbe esi idibo jade lori ayelujara ayafi ti wọn ba gba iyọnda lọdọ àjọ to n mojuto eto ibaraẹnisọrọ iyen NCC pe nẹtiwọki wa lati fi sebẹ.

Awọn aṣòfin tun fọwọ si pe awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ṣeto idibo abẹnu eleyi ti awọn ati INEC ṣetán láti fojú sí imusẹ rẹ.

Igbimọ ẹlẹni-meje kan ni ile asofin gbe kalẹ lati ṣe ìpàdé pelu ile Asoju sofin lati wo iyatọ to wa laarin ofin tó dé eto idibo Nàìjíríà,Electoral Act , tó wà nílẹ̀ ati eleyi ti wọn fẹ ṣàtúnṣe.

Ìyàtọ̀ to ba ofin idibo ni Naijiria

Nitori wàhálà jagidijagan ati jiji apoti ibo gbe tó máa n saba waye lasiko

idibo ni Naijiria, lo mu ki ile aṣofin agba gbe ìgbésẹ láti ṣàtúnṣe ofin tó dé eto idibo ni Nàìjíríà ni 2019.

Ile ṣàgbékalẹ̀ aba ofin kan ni 2019 eyi ti yóò ri pe INEC samulo fifi esi idibo ránṣẹ gba ayelujara.

Kiakia láwọn asofin ká ofin naa to sì yarade abala keji eto aba ofin.

Pẹlu atunṣe yii, ireti wa pé INEC yoo lo àtẹ orukọ oludibo gbogbo ti yoo wa lójú ayelujara.

Bakan naa ni wọn yoo fi èsi ranṣẹ nipa ojú òpó ayelujara yi kan náà