Olajide Sowore: Òpó kan ní òkú ọkọ òun lòun fẹ́ lọ sin kí òun tó kó ṣọ́wọ́ ajínigbé

Obinrin kan, Emmanuella Anyanwu, ti sọ pé àwọn agbegbọn to pa Olajide Sowore lopin ọsẹ to kọjá bere milliọnu mẹwàá naira owo itusilẹ lọwọ oun ki oun to moribọ nibi ti wọn ko wọn si.

Anyanwu ṣàlàyé pé òun ni rìnrìn àjò láti ìlú Eko sí ipinlẹ Imo lati lọ sin òkú ọkọ òun ni ki iṣẹlẹ naa to waye, òun sì fi N500,000 bẹ awọn ajinigbe naa ṣugbọn wọn kọ jalẹ.

Obìnrin opo naa ṣàlàyé ni agọ awọn ọlọpaa pe ọkọ awọn dẹnukọlẹ nítòsí ìlú Benin lọjọ náà lọhun, awọn sí sun inú ọkọ náà mọju.

O ni "Ni nnkan bíi aago mẹfa abọ idaji, awọn okunrin kan jade láti inú igbó, wọn sì bẹrẹ sí n yìnbọn sí wa, eyiti o mu ki a jọwọ ara silẹ fún wọn."

"Wọn ko gbogbo ẹrù wa, wọn sì kó wa lọ sínú igbó kiji kan ti irinajo rẹ tó nnkan bíi wakati meji."

Anyanwu sọ pe lẹyìn náà ni wọn bere onírúurú ibere lọwọ oun ki wọn tó sọ pé ajinigbe ni awọn, ti wọn sí ni àwọn yóò gba mílíọ̀nù mẹwàá naira owo itusilẹ lọwọ òun.

O ni ko pẹ diẹ sí asiko naa ti ojo bẹrẹ sí n rọ, ti wọn tun mu okunrin mii wa sinu ibudo náà ki oun to wa ọna lati sa asala.

Nigba to n sọrọ nípa irufẹ èèyàn tí awon ajinigbe naa jẹ, o ni oun gbagbọ pe Fulani ni wọn.

Gẹgẹ bíi ohun tó sọ, o ni "Mo gbagbọ pe Fulani ni wọn, nítorí lọjọ naa, wọn tú awọn màlúù wọn sílẹ kí wọn tó wà ji wa gbe."

Nigba ti awọn akọroyin bere lọwọ rẹ bóyá awọn to ji í gbé lo pa àbúrò Omoyele Sowore, o ni awọn ajinigbe naa yinbọn lu ọpọ ọkọ loju popo lásìkò ti iṣẹlẹ naa wáyé.

Anyawu pari ọrọ rẹ pé nígbà tí òun sa kúrò ní àhámọ́ awọn ajinigbe náà, opo ẹrọ ibaraẹnisọrọ kan ni oun tọ fún nnkan bíi wákàtí meji ki oun to pade okunrin kan to mu òun lọ sí àgọ ọlọ́pàá.