You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria debt profile: Níbi tí ìjọba àpapọ̀ ń bọ́rọ́ lọ àfàìmọ̀ káwọn tí Nàìjíríà jẹ ní gbèsè ó má fi ṣọfà, Atiku Abubakar ṣèkìlọ̀
Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Alhaji Abubakar Atiku ti ke si ijọba apapọ pe ẹsọ-ẹsọ ni ko ṣe lori amojuto iṣuna orilẹ-ede Naijiria lọna ati le e di ọjọ ọla awọn iran ti n bọ mu daadaa.Ìjọba Buhari fi N2.02tn san èlé orí gbèsè nínú N2.23tn tó wọlé sápò ìjọba lóṣù mẹ́fà
Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, eyi to pe akọle rẹ ni "A ko gbọdọ jẹ ki gbese mu Naijria nitori awọn iran to n bọ" ni Alhaji Atiku Abubakar ti sọ eyi.
O ni loṣu kẹfa, ọdun 2020 loun ti n pariwo soke lori bi gbese ṣe n fi ojoojumọ pọ si lọrun orilẹede Naijiria leyi to le e de ikorita koyeni mọ laipẹ.
- Àwọn olùgbé Akinyele fí ẹ̀sùn ilẹ̀ gbígbà kan ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, ìjọba Makinde ti fèsì padà
- Wo àwọn àwòràn láti ibi ètò ìsìnkú òṣèrébìnrin, Rachael Oniga
- Àwọn òbí ta dúkìá, ilé ẹ̀kọ́ Islamiya ta ilẹ̀ wá N61m owó ìtúsílẹ̀ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Tegina tó gbòmìnira
- Ìjọba Buhari fi N2.02tn san èlé orí gbèsè nínú N2.23tn tó wọlé sápò ìjọba lóṣù mẹ́fà
- Pòrò-pòrò ni omijé n dà níbi ètò ìsìnkú Mohammed, ọmọ Gani Fawehinmi
- Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí gúúsù Kaduna tún ti sọ̀rọ̀ pé ìkọlù sí iléeṣẹ́ ológun NDA kò jẹ́ ìyàlẹ́nu
Atiku ni nigba to tilẹ ti wa di eyi ti orilẹede Naijiria n fi ida aadọrun owo to n pawọle san gbese bayii, o fihan pe nnkan ko rọgbọ mọ ni o.
O ni ikilọ ti oun ṣe nigba naa ko lọwọ oṣelu tabi ohunkohun ninu bikoṣe gẹgẹ bi ọms orilẹede rere lati ta awọn alaṣẹ iṣuna Naijiria leti pe Naijiria ko gbọdọ wọ ọgbun gbese.
"Lọwọ ti a n ba lọ yii, orilẹede Naijiria ti n gbe ẹnu le pepele ti owo apawọle rẹ gan ko ni ka gbese sisan ọhun gan mọ. Eyi to tumọ si pe awọn taa jẹ ni gbese gan lee fẹ fiwa ṣọfa tọrọ ba kan karangida."
O ni bi a ko ba gbagbe, ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 ni ileeṣẹ to n mojuto aba iṣuna orilẹede Naijiria gbe atẹjade kan sita pe triliọnu meji o le igba ati ọgbọn biliọnu naira (N2.23 Trilion) ni Naijiria pa wọle laarin oṣu mẹfa akọkọ ọdun 2021, ati pe triliọnu meji o le igba miliọnu naira (N2.02 Trillion) ninu rẹ ni wọn fi san gbese.