Ogun state landgrabbers:Àwọn ajagungbalẹ̀ gba ilẹ̀ tó yẹ fún kíkọ́ iléèwé girama ní ìpínlẹ̀ Ogun

Ni ilu Isiun nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ni ipinlẹ Ogun, awọn ajagungbalẹ ti gba ilẹ ti wọn fẹ fi kọ ileewe girama nibẹ.

Gẹgẹ bi kabiyesi Olu ti ilu Isiun, Ọba Lawrence Adeyinka ṣe sọ ninu iwe ẹhonu to kọ si gomina ipinlẹ naa, Dapọ Abiọdun, ileewe girama Isiun High School ni wọn fẹ fi ilẹ naa kọ ki awọn ajagungbalẹ to lọ gba ilẹ naa.

Ọba Lawrence ni iṣẹlẹ naa ti n dena igbesẹ ati gbe ileewe naa, eyi ti gomina ipinlẹ naa nigbakan ri, Ọlabisi Ọnabanjọ da silẹ lọdun 1980 dide pada.

Ọba Olu ti ilu Isiun tun ṣalaye pe titi ti wọn ti ileewe naa pa ti mu ki awọn akẹkọọ lati ilu naa maa rin irin ọpọlọpọ kilomita lọ si awọn ileewe lawọn ileto to yi wọn ka ti awọn miran si wulẹ gbegi le iwe kika.

O nipatako afinimọna ti wọn ri siwaju ileewe naa lawọn kọlọransi naa ti wu danu ti wọn si ti n kọ ile sori ilẹ naa.