You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun
Agbara wa ninu ipenija ara, ohun to ba si wu nii se, bii idan lo n ri.
Muinat Abdulfatai ni ipenija oju lati kekere, ti ko si riran rara amọ okoowo iru to nira fun abarapa lati se gan lo dawọle.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to gbe de idi okoowo naa, Muinat salaye pe isoro ti oun koju nile ọkọ lo sun oun de ilw baba oun, ti oun si fi dawọle okoowo iru.
O ni ile ẹkọ ni oun wa ti wahala oju naa fi bẹrẹ, ti ọkọ oun fi fẹ oun amọ ko tọju oun rara, ti ẹrọ ata ti oun fi n se isẹ aje si bajẹ.
- Ẹ wo tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ àmọ́ tí wọn kọ̀ láti ṣe agbe jẹun
- Ìpèníjà ojú kò ní kí ń má ṣiṣẹ́ ‘DJ’ - Etu Sodiq Omotayo
- Àrà méèrírí! Ọkùnrin tí kò ríran kan rèé tó ń lọ ẹ̀rọ ata
- 'Pẹ̀lú ìpèníjà ara mi, mo kọ̀ láti ṣagbe'
- Wo tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ojú àmọ́ tó ń ṣiṣẹ́ ọwọ́
- Mo di afọ́jú lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí aya mi kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ - Wòlíì Oluwalogbon
- 'Dokita ilé ìwòsàn ló gba ẹsẹ̀ lọ́wọ́ mi'
- Ẹ má 'Pity' wa mọ́, Olorun ló dá àwa tí a ní 'Cerebral Palsy'- Olawale Dada, Oníṣòwò ilé títà
- 'Àwọn èèyàn sọ fún mi pé bí mo bá mọ ìyà ọmọ tó jáná, mi ò bá má bá a wí'
- Afọ́jú akẹ́kọ̀ọ́gboyè sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀
- Nígbà tí mo dàgbà ní mo rí i pé oore ńlá ní Olorun ṣe mi pẹ̀lú aàbọ̀ ara mi- Bose Okeowo
Idi ree to fi ni oun fi gbe majele jẹ lati tọrọ iku nigba ti ireti pin amọ Ọlọrun ko fun oun, ti ile iwosan si gba oun silẹ.
O ni idi isẹ iru tita ni oun pada si, ti oun si n fi bọ ara oun atawọn ọmọ pẹlu.
Nigba to n salaye awọn ipenija to wa nidi iru sise, Muinat ni oun ko le se agbe jẹun nitori oun naa fẹ gbe nnkan rere se nile aye, idi ree ti oun fi dawọle okoowo kan.
O ni oun ni eeyan kan to maa n ba oun sa okuta kuro laarin awọn iyere amọ oun gan maa n sa funra oun nipa mimu iyere ni ẹyọ kọọka.
Obinrin to ni ipenija naa ni atẹlẹwọ ẹni ni kii tan ni jẹ, oun ko si fẹ fi iya jẹ ara oun, ni oun ko fi tọrọ bara.