You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olumuyiwa Bolade Adedeji Military Bruitality: Bí arákùnrin onípèníjà ara tí sọ́jà lù ṣe dé
"Bi mo ṣe ni ipenija ara yii, mi o ro pe o yẹ ki sọja naa lee ṣiwọ lu mi rara amọ...".
Ọkùnrin kan nílùú Ibadan to ni Sójà obìnrin lù mí lálù bami nílùú Ibadan nílùú Ibadan lẹ́yìn tí òun ba ọmọ rẹ̀ wí pé ó fẹ́ jánà mọ́ mótò òun lẹ́nú ti dero ile iwosan bayii.
Gẹ́gẹ́ bi ọkùnrin tó ni ìpèníjà ara náà, Olumuyiwa Bolade Adedeji ṣe sọ fun akọroyin BBC niluu Ibadan, "Pasitọ̀ ni mi, oluṣiro owo si ni mi pẹlu. Bii ago meje abọ owurọ ni iṣẹlẹ yẹn ṣẹlẹ".
" Ọmọkunrin kan fẹ́ jána mọ́ móto mi lẹ́nu lójú pópó, "mo sọ̀kalẹ̀ nínú mótò mi láti ba ọmọ náà wi pé kí ó m a ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́".
- Adolf Hitler gbé àpótí ìbò, aráàlú yàn án sípò gẹ́gẹ́ bíi Káńsílọ̀
- Àrún ibà pónjú-pọ́ntọ̀ bẹ́ sílẹ̀! Ó ti pa èèyàn 172 ni Nàìjíríà - WHO
- Àwọn agbègbè tí àtùndi ìbò yóò kàn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta nípìnlẹ̀ Eko rèé
- Àwọn ohun tó bá lè fa ìwà ọ̀daràn bíi aṣọ ìwọ̀kuwọ̀ ló yẹ ká ti ọwọ́ rẹẹ̀ baṣọ - Amotekun Osun
- 'Àfi kí ìjọba gbẹ̀san àwọn Ọlọ́pàá Mopol tó pa Ọkọ mi, London Tailor lásìkò ìwọ́de EndSARS bí kẹ́ẹ̀ kọ́...'
"Ti kii ba ṣe Ọlọrun, nkan ta n wi yii kọ lao ba maa wi tori ọmọ to jana mọ ọkọ mi lẹnu yẹn ṣe e lojiji o si sunmọ gan".
Olumuyiwa ni ṣe lawọn eeyan to jade n sọ fun oun pe bi oun ba mọ ioya ọmọ ti oun n bawi yii, yoo tẹ lọwọ rẹ o tori kii ṣe ẹran rirọ.
"Ṣe ẹni naa jẹ Ọlọrun ni, koda bo jẹ Ọlọrun, maa pe e maa ba a sọrọ̀ tori bo ṣe fi ọmọ ọdun mẹrin nikan silẹ ko dara", iyẹn ni mo sọ o ti mo si fọwọ kan ọmọ ba a wi.
Ọjọ keji ọjọyii nigbe aye Olumuyiwa kii ṣe itan didun rara tori iye awọn to wa ke e lọna ti wọn si bẹrẹ si ni lu u bi i bara. Lara wọn ni sọja obinrin koda wọn fa irin to fi n gbiyanju lati rin gẹgẹ bii onipenija ara.
Bo ṣe pada to ni oun yoo pada wa lati gbẹsan tori oun ko tilẹ mọ idi ti gbogbo wọn fi n lu oun lo ba ri i ti obinrin naa ti wa ninu aṣọ sọja.
Iroyin yii ko lee dun lẹnu wa bii ti ẹnu ọlọrọ gangan ninu fidio yii.