You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Ọwọ́ àwọn afurasí ‘Sọ́jà’ tó kọlu ilé Igboho kò ri mú
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ni nkan ko fara rọ bayii nile ajijagbara nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Ighoho.
Iroyin ti a n gbọ lati ilu Ibadan ni pe awọn ajinigbe yabo ile Igboho to wa ni agbegbe Soka nibi ti wọn ti ji awọn eeyan gbe lọ.
Agbẹnusọ fun Igboho, Olayomi Koiki sọ ninu fidio kan to fi lede loju opo Facebook rẹ ṣalaye pe awọn janduku kan yabo ile Igboho nibi to sọ pe wọn ti pa eeyan.
- Jẹ́jẹ́ ni Iyabo Ojo jókòó, èmi ni mo pè é sí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Lola Alao
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- TAMPAN bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn igun tó ń bínú, ọ̀rọ̀ yóò yanjú láìpẹ́ - Femi Adebayo
- Sunday Igboho ní digbí lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu àti ìdásílẹ̀ Biafra
- Ta ló fẹ́ jí Auxilliary gbé ní Ibadan?
- Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìbẹ̀rù pé wọ́n le gbé Sunday Igboho lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ Nnamdi Kanu
- Eré wa ni kẹ wò, ẹ má wo aṣemáṣe àwa onítíátà - Olaiya Igwe
- Bíṣọ́ọ̀bù Enugu ní obìnrin ni wọ́n fi mú Nnamdi Kanu
- Ẹni tó bá tàbùkù àgbà níta, ti ń bú òbí rẹ̀ nílé tẹ́lẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
Koiki ni awọn janduku ọhun tun ji awọn eeyan lọ nile Ighoho to wa ni Soka, ti wọn si ba ọpọ mọto rẹ jẹ.
Lara awọn mọto to sọ pe awọn afurasi janduku naa bajẹ ni ọkọ olowo iyebiye G-Wagon, Prado Jeep atawọn ọkọ miran to wa ninu agbala rẹ
Koiki ni awọn afurasi sọja to yabo ile naa ko gbogbo owo to wa ni ile Ighoho lọ. O ni oriṣiiriṣii ọta ibọn lo wa nilẹ tawọn janduku agbebọn ọhun lo nile Igboho.
Ọpọ eeyan lo ti sọ lori ayelujara lati bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.
Awọn janduku ọhun wa gbogbo inu ile lati mu Igboho ṣugbọn wọn ko ri Igboho.
Gbogbo awọn to wa ninu ile Igboho ni wọn jigbe lọ to fi mọ awọn to n dana ounjẹ ni ile rẹ to wa ni Soka,'' Koiki ṣalaye.
O ni oriṣiiriṣii ọta ibọn lo wa nilẹ tawọn janduku agbebọn ọhun lo nile Igboho.
''Awọn janduku ọhun ba gbogbo ọkọ to wa nile Sunday Igboho jẹ patapata.
Awọn janduku ọhun wa gbogbo inu ile lati mu Igboho ṣugbọn wọn ko ri Igboho.
Gbogbo awọn to wa ninu ile Igboho ni wọn jigbe lọ to fi mọ awọn to n dana ounjẹ ni ile rẹ to wa ni Soka,'' Koiki ṣalaye.
Koiki fi kun ọrọ rẹ pe ohun ti awọn n gbọ ni pe o ṣeeṣe ki awọn sọja to yabo ile Igboho tun pada wa.
''Mo le sọ pe ijọba orilẹedee Naijiria lo ran awọn sọja wa si ile Sunday Ighoho.
Wọn pa awọn eeyan nibẹ, wọn si ti ko oku awọn eeyan ti wọn pa nile Sunday Igboho lọ.
N ṣe lawọn sọja naa di oju titi pa niwaju ile Igboho, ki wọn to yabo ile rẹ,'' Koiki lo sọ bẹẹ.
Bi iroyin naa ba se n lọ, la maa mu wa fun yin.