Igisekele: Àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ akọrin Fuji ń ṣèdárò Amoo Igisekele tó jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eekan akọrin Fuji lorilẹede Naijiria, Alhaji Taofeek Adewale Amọo Igiṣekele ti jade laye.

Igiṣekele ju gbohungbohun silẹ fun igba ikẹyin lorilẹede Amẹrika, lọjọ Satide ni awọn iroyin to jẹyọ lori iku akọrin Fuji naa sọ pe o jade laye.

Awọn iroyin abẹle kan sọ pe aisan iba lo ṣekupa olorin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alhaji Igiṣekele jẹ ọkan lara awọn gbajugbaja olorin ti ọpọ mọ, koda ọpọ lo mọ ọ gẹgẹ bi ara awọn olorin to wa ni sawawu King Wasiu Ayinde Marshall, KWAM1.

Nigba aye rẹ, oniruuru ipenija lo dojukọ Alhaji Igiṣekele nile ati loke okun. Iroyin kan tilẹ gbe pe laarin ọdun 2012 si 2013, wọn fi ofin de e pe ko gbọdọ wọ ilẹ Gẹẹsi.

Amọṣa iroyin naa sọ pe o tẹ oju ofin mọlẹ nigba naa.

Iwe igbelu rẹ nigba naa kii ṣe ọlọjọ gbọọrọ, eleyi to nilo ontẹ igbelu tuntun loorekoore ni, eleyi ti ko si fun un laaye lati pẹ lẹyin odi orilẹede naa ju bo ti ṣe yẹ lọ.

Orilẹede Amẹrika ni Alhaji Igiṣekele tẹdo si, ilu Newark lorilẹ̀ede Amẹrika lo si n gbe titi di ọjọ iku rẹ.

Ọmọ agbole Alagolo lagbegbe Ọjaaba nilu Ibadan ni akọrin Fuji naa.

Ni bayii, ọpọ awọn ololufẹ orin Fuji ni wọn ti n ba awọn olorin naa daro.

Agba olorin miran, Taye Currency lo tufọ iku rẹ loju opo Facebook rẹ. Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ohun to ba ni ninu jẹ pupọ ni iku olorin naa.

Lara awọn eekan olorin mii ti wọn ti bọ sita sedaro Igiṣekele ni Saheed Oṣupa wa.

Ninu atẹjade ti Oṣupa fi soju opo rẹ lo ti ni, "iku ni opin ohun abẹmi gbogbo, amọ inu Ọlọrun ni itunu wa lori iku arakunrin wa Taofeeq Adewale Amọo Igiṣekele"