You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ademola Adeleke: Sẹ́nẹ́tọ̀ Ademola Adeleke kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní fásítì l'Amerika
Njẹ ẹ ranti sẹnẹtọ onijo? Eyiun ni, Ademola Adeleke to jẹ oludije fun ipo gomina ninu idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2018.
Sẹnẹtọ Adeleke ti kawe gboye ni fasiti lorilẹede Amerika lopin ọsẹ yii.
Ademola to jẹ aburo baba olorin takasufe, Davido ro dẹdẹ, bẹẹ lo kan dudu nibi ayẹyẹ ikẹkọjade ni fasiti to ti gboye l'Amerika.
- Àwọn ẹni ibi kan ń wá gbogbo ọ̀nà láti tú orílẹ̀èdè Nàíjíríà ká - Ààrẹ́ Buhari
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
- Ẹbí Adeboye kéde bí ìlànà ikú Pásítọ Dare yoo ṣe lọ
- Akeredolu, jọ̀ọ́ gba iṣẹ́ lọ́wọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ tó lu aláboyún - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yarí
- Wo ìhùwàsí Buhari, àwọn èèkàn Nàìjíríà àti ibòmíì tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
Sẹnẹtọ onijo ko ṣai fi idunnu rẹ han loju opo Instagram rẹ.
Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun lọsun 2018 kọọ soju opo Instagram rẹ pe Ọlọrun dara ni gbogbo igba.
Ọrẹ, ojulumọ ati ẹbi to fi mọ ẹgbọn Sẹnẹtọ onijo, Adedeji Adeleke ati ọmọkunrin rẹ, BRed lo wa nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade naa lorilẹede Amerika.
Ẹwẹ, idile atawọn ọrẹ fi ẹsẹ ra ijo lati ba Ọgbẹni Ademola yọ lori aṣeyọri rẹ.
Koda, ẹgbẹ rẹ Adedeji naa ko gbẹyin, bakan naa ni Ademola fun ra n mi lẹgbẹ.