You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Chris Oyakhilome: £125,000 ní owó ìtanràn tí Tẹlifísàn Loveworld yóò san fún ìwà arúfin
Ajọ to n se akoso eto igbohunsafẹfẹ nilẹ United Kingdom ti kesi ileesẹ mohunmaworan pasitọ kan ni Naijiria, Chris Oyaklome lati sanwo itanran.
Ileesẹ mohunmaworan naa, Loveworld Television Network, ni wọn ni ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna marundinlaadoje pọnun 125,00.
Ẹsẹ ti wọn ka si ọrun ileesẹ agbohunsafẹfẹ naa ni pe o gbe eto kan sita lori ọrọ ẹsin, ninu eyi ti wọn ti n sọ awọn ofege iroyin nipa arun Coronavirus lai daabo bo awọn onworan wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá
- Àbọ̀ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l‘Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ
- Wo àbọ̀ ìwádìí Amẹ́ríkà lórí ìkọlù ológun tó wáyé ní Lekki
- Àwọn tí àkóso ìjọba bọ́ lọ́wọ́ wọn ló ń ti Igboho lẹ́yìn lórí ìdásílẹ̀ Oodua Nation - YWG
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- "Nǹkan tó lé pa màálù 30 lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lé pa ènìyàn, ẹ̀yin àrá Ondo, ewu ńbẹ"
- Àwọn agbébọn pa ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá, ṣọ́jà, wọ́n tún jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ní Akwa Ibom
Ajọ naa ni igba keji ree laarin ọdun tileesẹ naa yoo tako ofin to rọ mọ gbigbe ojulowo iroyin lai ni abula sori afẹfẹ, eyi to n tako iroyin gidi nipa arun Coronavirus.
"A ri awọn iwa riru ofin yii bii eyi to gbopọn pupọ ati iwa asise mase to n foju han lọpọ igba eyi to mu ka ta ileesẹ igbohunsafẹfẹ naa loji owo."
Ileesẹ ijọ UK to n sakoto awọn ileesẹ igbohunsafẹfẹ naa ni oun to n kọ oun lominu ni pe igba akọkọ kọ ree tileesẹ amohunmaworan Loveworld yoo tasẹ agẹrẹ si ofin awọn.
O ni irufẹ iwa arufin naa ti kọkọ waye lọdun 2020, tileesẹ tẹlifisan Loveworld si fi ọwọ gbaya pe oun yoo mu ibọwọ fun ofin lọkunkundun lai se bẹẹ.