Florence Onwuasoanya: Mo jẹ́ àsejẹ, mo mu àgbo tí kò ṣe e fẹnu sọ kí ń lè gbé ọmọ jó ṣùgbọn...

Florence sọrọ nipa gbigbe lagboole ti ero pọ si ati iṣoro rẹ fun ẹni to n woju Oluwa

Florence Onwuasoanya ni abiyamọ to sọ ohun ti oju rẹ ri to lọwọ ẹjẹ ti oloyinbo n pe ni " Rhesus Negative" ni eyi to fi n sunkun asunrin.

Agboole nibi ti awọn obinrin bii meje si mẹjọ ti jọ n loyun lasiko kan naa ni Florence n gbe.

Pẹlu omije kikoro ati si ọpẹ Florence sọ nipa irinajo aye rẹ ati igbiyanju gbogbo to ṣe lati ri ọmọ gbejo gẹgẹ bii alaaye.

O ni: Gbogbo èèyàn lo n gbe ọmọ wale lẹ́yìn ibimọ ṣugbọn irinajo tèmi ko ri bẹ́ẹ̀.

Ilé mi túká, àyọ mi sọnù, ìdúnnú dàwátì, ọkọ pè mi ní àgbàná, ará ilé pè mi ní emere, Ogbanje nítorí ọmọ bíbí

Arabinrin Olufunlayo Banire to jẹ oludasilẹ ajọ to n pese iranlọwọ nipa Rhesus naa ba BBC sọrọ lori koko yii ati ipenija rẹ fun obinrin,

O gba ijọba Naijiria ni imọran lati pese abẹrẹ to yẹ lọfẹẹ fawọn obinrin.

Florence fi orin ọpẹ si Oluwa pari rẹ pe lẹyin igbesẹ to yẹ oun pada bi ọmọkunrin lantilanti to ti pe ọdun mẹwaa bayii ki eledumare baa woo ni awoye.

Ma ṣe ro ara rẹ pin ṣugbọn wa imọ kun imọ lori ohun to ba n yọ ẹ lẹnu gẹgẹ bii obinrin.