Rashidi Ladoja: Èmi kìí ṣe olóṣèlú mọ́, n kò sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kankan

Gomina ana nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Rashidi Ladoja ti asalaye idi to fi ls se abẹwo si gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Abẹwo naa eyi to ti n fa awuyewuye lori ayelujara ni Rashidi Ladoja ti wa kede pe ko ni nnkan se pẹlu eto idibo ọdun 2023.

Akọwe feto iroyin fun Sẹnetọ Ladoja, Lanre Latinwo sọ lọjọru pe Rashidi Ladoja lọ sile Tinubu lati ba kẹdun lori ọpọ dukia to padanu lasiko rogbodiyan EndSARS nilu Eko ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa yan pe ko si ohun to jọ mọ ọrọ oselu rara ninu ijiroro awọn agba oselu mejeeji naa lasiko abẹwo ọhun .

Latinwọ ni Ladoja lo fi oko kan pa ẹyẹ meji lasiko irinajo rẹ silu Eko naa, ẹni to fi ẹsẹ kan ya sile Tinubu lati ba kẹdun lasiko ti agba oselu naa lọ sibi ayẹyẹ isisnku kan nilu Eko.

Bakan naa lo tun foju laifi wo ọrọ kan to ni igbesẹ Ladoja naa tako ofin ẹgbẹ oselu rẹ, pẹlu afikun pe oloye Ladoja kii se oloselu mọ, ti ko si kede inu ẹgbẹ oselu to wa fun ẹnikẹni.