Abike Dabiri-Erewa: Ìròyìn òfégè ní pé mò kò "Palliatives"pamọ́ sí ilé mí

Alaga ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria lẹyin odi, Abike Dabiri Erewa ti ke gbajare lori iroyin to gbode pe o ko awọn nkan iranwọ Covid-19 pamọ sile rẹ.

Abike Dabiri-Erewa sọ pe iroyin ofege gbaa ni ọrọ yi.

Dabiri fesi si ọrọ yi ni idahun si ibeere akọroyin ile iṣẹ iroyin Vanguard lasiko idibo atundi to waye nipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta.

Dabiri ni ẹsun toun ko mọwọ mẹsẹ ni wọn fi n kan oun.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ti ṣe sọ, wọn ni awọn kan ti ko foju han lo gbe iroyin naa sita loju opo ayelujara pe Dabiri ko awọn nkan iranwọ yi pamọ si ile rẹ to wa ni GRA Ikorodu.

Bẹẹ naa lo fi kun pe iroyin ofege naa tọka pe Abike Dabiri kọ orukọ oludije sipo Sẹnẹtọ Tokunbo Abiru si ara awọn nnkan iranwọ Covid yii.

Ninu idahun rẹ, Abike Dabiri ni '' O ya mi lẹnu lati kaa wi pe mo ko Palliatives pamọ sile.Ko bimi ninu ṣugbọn mi o ro pe o yẹ ka wa ba ọmọluabi jẹ nitori oṣelu''

Nigba ti BBC kan si Sẹnẹtọ Dabiri loju opo Whatsapp rẹ lati fesi si ọrọ yi, o fi aworan iroyin naa ranṣẹ lai sọ nkan mii mọ.