Abike Dabiri vs Pantami: Èrò ọmọ Nàìjíríà sọ̀tọ̀tọ̀ lórí fàákájáa láàrin Abike Dabiri-Erewa àti mínísítà ètò ìbárẹ̀nisọrọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọ̀rọ̀ sọ̀tọ̀tọ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí igbésẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ méjèèjì ti wọ́n léra síta lórí ayélujára lórí ọ̀rọ̀ tó yẹ kí wọ́n yanjú láì jẹ kí etí míràn gbọ́ síi tí wọ́n tahùn síra wọn lórí àtẹ̀jísẹ́ Twitter Fọ́nrán kan ló kọ́kọ́ jẹ yọ níbi tí ile ișẹ́ ìròyìn Sahara ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí bí ilé iṣẹ́ to rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ṣe n sojúṣe wọn àti pé àwọn ìpèníjà wo ni wọ́n n kojú lásìkò yìí

Nínú èsì rẹ̀ alága àjọ tó n rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè Abike Dabiri-Erewa ṣàlàyé pé mínísítà fún ẹ̀rọ ìbárẹ̀nisọrọ̀, Isa Ali Pantami fi ìbọn le òun àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ síta nínú ọ́fíìsì ìjọba, lásìkò tó n rin ìrìn àjò lọ si ilẹ̀ òkèrè.

Ó ní títí di àsìkò yìí àjọ òun kò lọ́fììsì, gbogbo àwọn irinsẹ́ ọlọ́dani tí àwọn sì n lò ló wà ní títì pá títí di àsìkò yìí. Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ọ̀rọ̀ yìí jáde ní mínísítà náà ba fèsì pé irọ́ pọ́nbélé tó jìnà sóòtọ́ ni ọ̀rọ̀ Abike Dabiri. O ni ẹ̀rí wà lorisirisi láti gbé ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn pe irọ ni Dabiri-Erewa n pa.

Èyí tí wá dọ̀rọ̀ a n gbà bí ẹní n gbagbá otí lórí ẹ̀rọ àtẹ̀jísẹ́ Twitter báyìí, olúkúlùkù sí n sọ èrò tirẹ̀. Àwọn ọmọ Nàìjíríà ní bí ẹni pé ènìyàn n fọṣọ ìdọ̀tí rẹ̀ níta gbangba lọ̀rọ̀ náà rí to sì tini lójú gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè.

Kódà àwọn míràn tí ṣèdájọ́ ojú ẹsẹ̀ tí pé o yẹ kí ààrẹ gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Pantami ni fún irú igbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Àwọn míràn tún fa ẹ̀rí fọ́nrán mìíràn síta pé ìpàdé ri àwọn òṣìṣẹ́ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n lé wọn jáde lọ́fììsì lásìkò tí Abike Dabiri ò sí nílé.

Ọ̀pọ̀ tilẹ̀ ni pé isó inú ẹ̀kú ni ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà kò to sí Abike Dabiri láti sọ ǹkan tí ojú rẹ̀ bá rí lọ́wọ́ ìjọba yìí.