LAUTECH: Ìgbésẹ̀ pínpín dúkìá àti gbèsè fásitì LAUTECH ti bẹ̀rẹ̀

Ọrọ aawọ laarin ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun lori ta lo ni fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintọla ti jẹrodo lọ mumi bayii pẹlu bi ajọ to n ṣamojuto fasiti lorilẹede Naijiria, NUC ti ṣe kede rẹ lọjọ Ẹti pe ipinlẹ Ọyọ ni yoo maa gba akoso fasiti naa bayii.

Bakan naa lo tun kede rẹ pe, ileewosan nla ti fasiti naa iyẹn, LAUTECHTH to wa ni ilu Oṣogbo yoo jẹ ti ipinlẹ Ọṣun.

Ni ọdun 1990 ni wọn da fasiti naa silẹ labẹ ipinlẹ Ọyọ atijọ. Ilu Ogbomọṣọ ni wọn gbe Ọgba ikọni fasiti naa si ki wọn to lọ da ile ẹkọṣẹ iṣegun rẹ si Oṣogbo.

Amọṣa nigba ti wọn da ipinlẹ Ọṣun silẹ lati ara ipinlẹ Ọyọ atijọ lọdun 1991, awọn ipinlẹ mejeeji bẹrẹ eto ajumọni lori fasiti naa.

Akọwe agba ajọ NUC, Ọjọgbọn Abubakar Rasheed ṣalaye nilu Abuja pe ipenija to n waye lori akoso fasiti naa laarin awọn ipinlẹ mejeeji yii to si n mu idiwọ ba yiyan giwa atawọn agba oṣiṣẹ miran ni fasiti ọhun pẹlu sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ lasiko lo ṣokunfa pinpin ti wọn pin akoso rẹ.

Ọjọgbọn Abubakar Rasheed tun jẹ ko di mimọ pe awọn gomina ipinlẹ mejeeji lo finufindọ buwọlu iwe adehun lori pinpin iṣakoso fasiti naa.

O ni igbesẹ lori pinpin awọn dukia ati gbese to wa lọrun ileewe fasiti naa laarin awọn ipinlẹ mejeeji ti bẹrẹ.