Rahama Sadau blasphemy: Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn rèé nípa bóyá wọ́n dájọ́ ikú fún òṣeré Kannywood

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Osere tiata Kannywood kan, Rahama Sadau ti figbe ta pe ko si ẹnikẹni to mu oun ati pe, ofege ni iroyin to gbode pe wọn ti dajọ iku fun un.

Sadau fi ikede yii sita loju opo rẹ ni Twitter rẹ nirọlẹ ọjọ iṣẹgun.

Ikede rẹ naa ko ṣẹyin bi iroyin ṣe gba ori ayelujara kan pe wọn ti gbe osere tiata naa lọ si ileẹjọ Sharia, ti wọn si dajọ iku fun tori pe o ṣatọna bi awọn kan ṣe sọrọ abuku si Anọbi Muhammad.

O ni ''Mi o mọ ibi ti iroyin yi ti wa. Mo si rọ awọn eeyan lati sinmi ahesọ ọrọ ti ko nidi."

Lọsẹ to kọja ni Rahama ṣe alabapin awọn aworan rẹ kan to fara rẹ silẹ loju opo ayelujara.

Bi awọn eeyan kan si ṣe n gbosuba kare fun lori aworan yii, ni awọn miran n bẹnu atẹ lu.

Aworan naa da awuyewuye silẹ, tawọn eeyan kan si n sọrọ abuku si Anọbi Muhammad ninu ọrọ ti wọn kọ sabẹ aworan naa loju opo Twitter Rahama.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko si ẹnikankan to mu mi:

Amọ bi awọn eeyan kan ṣe n pe Rahama Sadau lori ago nipa idajọ iku ti wọn gbọ pe wọn se fun, lo mu ko bọ si oju opo Twitter rẹ lati salaye pe wọn ko mu oun.

''Awọn ọlọpaa ko fiwe pe mi, bẹẹ si ni mi o gba iwe ipẹjọ kankan. Mo fẹ fi da awọn ololufẹ mi loju pe alaafia ni mo wa, ko si si ẹjọ kankan ti wọn fi kan mi''

''Fawọn to fẹ sọ ọrọ yii di bamii, ti o le mu wahala wa, mo bẹ yin, ẹ tọwọ ọmọ yin ba sọ''

O fi kun ọrọ rẹ pe ''asiko yi jẹ akoko inira fun mi. Kii ṣe igba yii lo yẹ ka tun maa tan iroyin ofege ka. Mo dupẹ lọwọ awọn to kan si mi''