End SARS Protest: Babangida ní ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìsẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn tó ń wáyé káàkiri Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Adari orilẹede Naijiria labẹ ijọba ologun nigba kan ri, Ọgagun Ibrahim Babangida ti ni ko si rogbodiyan kankan to le bẹ silẹ ju wakati mẹrinlelogun lo ti ko si ọwọ ijọba nibẹ.

Ọgagun Ibrahim Babangida lo fi lede bẹẹ loju opo Twitter rẹ, lẹyin ti awọn ipinlẹ kaakiri orilẹede Naijiria n koju rogbodiyan lasiko ifẹhọnuhan tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Babangida ni oun sọ ọrọ ti Ọgagun Sani Abacha sọ nigba aye rẹ pe '' ti rogbodiyan ba ti ju wakati mẹrinlelogun lọ, oṣiṣẹ ijọba kan wa ni idi iṣẹlẹ naa niyẹn.''

O fikun un wi pe adari rere lo le e tukọ orilẹede Naijiria lasiko ti a wayii, nitori iru iṣẹlẹ bayii ni o ma n fihan boya eniyan jẹ adari rere abi bẹẹ kọ.

Bakan naa ni Babangida bu ẹnu atẹ lu iṣekupani awọn afẹhọnuhan lorilẹ-ede Naijiria nigba ti awọn ikọ Ologun Naijiria da ibọn bo wọn ni agbegbe Lekki Tollgate ni ilu Eko ati kaakiri Naijiria pẹlu.

Babangida ni kosi ọmọ Naijiria kankan to yẹ ko sọ ẹmi rẹ nu lori pe oun bere fun ẹtọ rẹ lọwọ ijọba tiwantiwa.

2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo

Oyedepo ní àwọn ọ̀dọ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti tako bí ọlọ́pàá ṣe ń pa wọ́n ní ìpakúpa

Biṣọọbu Oyedepo jẹ ọkan pataki lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni Naijiria ti kii fi ọrọ sabẹ ahan sọ lori ojuṣe tabi aṣiṣe ijọba

Pasitọ agba ninu ijọ Living Faith lagbaye, David Oyedepo ti da si ọrọ iwọde End SARS to n lọ kaakiri awọn ilu nla nla ni Naijiria.

Oyedepo sọ pe digbi ni oun wa lẹyin awọn oluwọde naa nitori gbogbo eeyan lo ni aṣẹ labẹ ofin lati fi erongba wọn sita nipa ifẹhonuhan.

David Oyedepo kede bẹẹ ninu iwaasu rẹ to se laarọ ọjọ isinmi oni ni olu ijọ rẹ to wa nilu Ota.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Biṣọọbu naa ni, bo tilẹ jẹ pe oun ti fi igba kan dakẹ lori ọrọ Naijiria, ṣugbọn oun ti kilọ ṣaaju ninu ọdun 2015 pe, ewu n bẹ loko longẹ ni Naijiria, ati pe gudugbẹ kan yoo ja laipẹ.

Oyedepo ni "Akoko to buru ju ninu itan orilẹ-ede yii ni ọdun marun un ṣẹyin, ti wọn n pa eeyan ni ipakupa."

O ni bayii ti wọn ti bẹrẹ si n pa awọn ọdọ ni ipakupa, wọn lẹtọọ lati sọ pe o to gẹ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, o ti le ni ọsẹ kan ti awọn ọdọ kaakiri Naijiria ti gunle ifẹhonuhan, lori bi awọn oṣiṣẹ ẹka to n gbogun ti iwa idigunjale ni ileeṣẹ ọlọpa, SARS, ṣe pa awọn eeyan lọna aitọ.

Oriṣiriṣi awọn gbajumọ ni Naijiria ati lawọn orilẹ-ede miran lagbaye lo ti n ṣegbe lẹyin iwọde ọhun.

Biṣọọbu Oyedepo jẹ ọkan pataki lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni Naijiria ti kii fi ọrọ sabẹ ahan sọ lori ojuṣe tabi aṣiṣe ijọba.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Sọ̀rọ̀ sókè! Odunlade, Toyin dásí ìwọ́de #EndSARS, Mercy gbébọn

Ọrọ ifẹhonuhan awọn ọdọ lori ati fi opin si ọlọpaa SARS ati SWAT ti ijọba ṣẹṣẹ yi orukọ wọn pada si ko yọ ẹnikankan silẹ mọ o.

Ọpọ olorin takasufe bi Davido, Falz, Wizkid atawọn adẹrinpoṣonu bii Mr Macaroni, Woli Agba lo ti darapọ mọ iwọde #EndSARS.

Amọ, awọn oṣere ori tiata Yoruba naa ko gbẹyin nibi iwọde ọhun.

Wọnyii lawọn oṣere ori itage Yoruba tawọn naa n kopa ninu ifẹhonuhan #EndSARS to n lọ lọwọ:

Odunlade Adekola

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Odunlade Adekola palẹ awọn akẹgbẹ rẹ naa bọ soju popo lati ṣe iwọde #EndSARS ati SWAT.

Niṣe ni Odunlade gbe gbohungbohun dani to fi n sọrọ nibi iwọde naa.

Bakan naa ni Odunlade tun gbe beba ninu eyi ti wọn kọ oriṣiiriṣii nkan si bii ''ọlọpaa, ẹ dẹkun ifiyajẹni, ipaniyan, ẹ ṣe atunṣe ileeṣẹ ọlọpaa,'' ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ijebu

Gbajugbaja oṣere meji Ijebu ati Afeez Owo lo jọ di beba kan ti wọn kọ ''END SARS NOW'' si dani ninu iwọde #EndSARS naa ni.

Bakan naa ni wọn daṣa ''sọrọ soke'' to lu oju ayelujara pa bayii.

Awọn naa n sọ pe opin gbọdọ de ba ijọba buruku lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi awọn oluwọde mii ṣe n sọ.

Toyin Abraham

Ilumọọka oṣere, Toyin naa ko gbẹyin nibi ifẹhonuhan #EndSARS.

Toyin sọ ninu iwọde naa pe ijọba gbọdọ tẹti si ohun tawọn oluwọde n beere fun.

O ni SARS ati SWAT gbọdọ wa si opin lorilẹede Naijiria lai beṣu bẹgba.

Mercy Aigbe

Aworan ibi to ti gbe ibọn dani to si duro niwaju ọkọ awọn ọlọpaa ni gbajugbaja oṣere Mercy Aigbe fi si oju opo Instagram tiẹ.

Mercy sọ pe oun n duro de asiko ti wiwọ aṣọ ọlọpaa ninu ere tiata yoo jẹ nkan iwuri fun oun.

Oun naa kepe ijọba lati fopin si iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa SARS.

O ni opin gbọdọ de ba ọlọpaa SARS ati SWAT ti ijọba ṣẹṣẹ yi orukọ wọn pada si.