You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSars protests: Fọ́tò àti ìtàn èèyàn tí ikú wọ́n ní ọ́wọ́ ọlọ́pàá Nàìjíría nínú
Iwọde ẹ fi opin si ọlọpaa Sars #ENDSARS, to wọ ọjọ kẹrin bayii, o ti bẹrẹ lati Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwa, ọdun 2020, kaakiri Naijiria.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti n polongo, beere fun idajọ lori iku awọn araalu to jẹ alaiṣẹ, amọ ti ileeṣẹ ọlọpaa pa.
Awọn ọdọ ti ṣe iwọde ni awọn asiko kan lati fi aidunnu wọn han si iwa ifiyajẹni ti awọn ọlọpaa ma n hu, ti wọn si n polongo fun fifi opin si ẹka ọlọpaa SARS.
Iwọde to n waye lasiko yii kii ṣe laarin ilu nikan, wọn gbe iwọde naa de ori ayelujara pẹlu ami idanimọ #ENDSARS. Eyi si ti mu ki ọrọ naa de akiyesi ọpọ ilumọọka ni Naijiria ati ilẹ okeere.
Koda, awọn ọmọ ilẹ okeere kan, ati awọn ọmọ Naijiria to n gbe nibẹ ti darapọ mọ iwọde naa.
Jimoh Isiaq
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwa, ọdun 2020 ni ibọn ba Jimoh Isiaka, lasiko iwọde #ENDSARS to waye nilu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Oyo.
Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn kọ lo yinbọn mọ ọdọmọkunrin naa.
Iku rẹ fa awuyewuye lori ayelujara, ti ọpọ eeyan si n sọ pe ko tọ ọ bi awọn ọlọpaa tun ṣe yinbn paayan lasiko ti iwọde n waye tako wọn.
Kazeem Tiamiyu
Igbakeji Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars ni Kazeem Tiamiyu, ko to o kagbako iku ojiji nilu Sagamu, nipinlẹ Ogun.
Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ fi ikede sita pe awọn ọlọpaa SARS kan fi ẹsun jijẹ onijibi kan Kazeem, koda lẹyin to fi kaadi idanimọ rẹ han wọn.
Lasiko ti wọn jọ n ṣe ariyanjiyan yii ni wọn ti i jabọ ninu ọkọ wọn, ti ọkọ miran si gba.
Ẹni ọdun mọkanlelogun ni nigba to ku l'oṣu Keji, ọdun 2020.
Tina Ezekwe
Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2020 ni Tina Ezekwe ku, lẹyin ọjọ diẹ ti ọlọpaa kan ti wọn sọ pe o mu ọti yo.
Lo ba yinbọn mọ ọ lasiko to n gbiyanju lati mu awakọ kan to ru ofin isede coronavirus nilu Eko.
Iku Tina mu ki awọn eeyan faray pupọ, ti wsn si fi #JusticeforTina beere fun idajọ lori iku rẹ, lori ayelujara.
Chibuike Daniel Ikeaguchi
Ẹni ogun ọdun ni Chibuike Daniel nigba to ku.
Akọrin ni, ti awọn eeyan mọ orukọ inagijẹ rẹ si 'Sleek'. Koda, o sṣe idanwo aṣewọle sileewe giga ni Naijiria, JAMB l'ọdun 2020.
- Ẹni méjì kú, ọ̀pọ̀ dèrò ilé ìwòsàn níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní Okokomaiko nípínlẹ̀ Eko
- Ó sàn fún mi kí n má tíì lọ́kọ báyìí ju kí n lọ́kọ ṣùgbọ́n...- Nkechi Blessing
- Ọ̀rẹ́ wa ni Lawrence jẹ́, àmọ́ ó gbẹ̀yìn dẹ́nu ìfẹ́ kọ abúrò wa - Joshua àti Damilola Bamiloye
- Akeredolu ti mókè nínú ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ méjìlá l‘Ondo, PDP gba mẹ́ta
Ẹgbọn rẹ, Maureen Ikeaguchi, to ba BBC Pidgin sọrọ, sọ pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2020, ti isẹlẹ naa waye, Sleek lọ ṣe abẹwo si ọrẹ rẹ kan ni adugbo Elelenwo, nijọba ibilẹ Obio Akpor, nipinlẹ Rivers.
Wọn ri awọn ọlọpaa ẹka to n risi ijinigbe, amọ wọn ro pe awọn ọlọpaa SARS ni. Bi wsn ṣe n gbiyanju lati salọ kuro nibẹ, ni ọkan lara awọn ọlọpaa naa yinbọn mọ aburo rẹ, to si yọri si iku fun.
Kolade Johnson
Adugbo Onipetesi, nilu Eko, ni ibọn ti ba Kolade Johnson, ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2019.
Ibọn ti awọn ọlọpaa ẹka to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun yi lo ba Kolade, ni ibudo kan ti wọn ti n wo ere bọọlu.
Iku tiẹ naa fa ariwo lori ayelujara.
Mus'ab Sammani
Ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2019, ni ọjọ ti oko ibanujẹ wọ inu ẹbi Sammani Zangon Marikita, nilu Kno.
Ibọn ọlọpaa naa lo sọ ọmọkunrin naa di eero ọrun lọsan gangan.
Gẹgẹ bi ohun ti baba rẹ sọ fun BBC, ẹni ọdun mejilelọgọrun ni Musáb, to si jẹ pe oṣu mẹrin ṣaaju iku rẹ lo pada si orilẹ-ede Naijiria, lati India to ti lọ kẹkọọ nipa imọ kọmputa.
Awọn ti iṣẹlẹ iku rẹ ṣoju sọ fun BBC Pidgin pe ọlọpaa kan to n ṣọ banki lo yinbọn mọ ọmọkunrin naa nitori ede aiyede to n waye laarin oun ati awakọ kẹkẹ kan to kọlu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.
Chioma Ikwunado
Ẹsun idigunjale ni awọn ọlọpaa mu Chima fun, nipinlẹ Rivers, amọ ahamọ ti wsn fi si lo ku si.
Ẹgbọn Chima, Anthony Ikwunado sọ fun BBC pe awọn ọkunrin mẹrin miran ti wọn mu pẹlu Chima sọ pe ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2019, lo ku.
O ni "wọn fi iya jẹ Chima, wọn kan ẹsẹ rẹ. Koda wọn sọ fun mi pe niṣe ni wọn so o mọ oke aja fun wakati meji ti wọn fi lọ fun irinkiri wọn. Igba ti wọn de ti wọn tu u silẹ, niṣe lo jabọ lulẹ bi odi kókò. Lẹyin naa ni wọn gbe sinu ọkọ wọn, ti wọn si gbe e lọ.
Ogah Jumbo
Iyawo Ogah, Ada, sọ fun ileeṣẹ BBC Pidgin pe lasiko ti ọkọ rẹ n gbe oun ati smọ lọ sileewe, lo ni aawọ pẹlu awọn osṣiṣẹ to n dari ọkọ loju popo.
O ni ko to iṣẹju melo ti wọn fi bẹrẹ si ni fi kondo lu u, ti wọn si tun wọ nilẹ lọ si agọ ọlọpaa.
Iṣẹlẹ naa to waye ni ogunjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2019, lo yọri si iku rẹ.