You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nkechi Blessing: Gbajúgbajà òṣèré ní ó sàn fún òun láì tíì lọ́kọ báyìí ju kí òun lọ́kọ láì láyọ lọ
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Nkechi Blessing tun ti ja gudugbẹ ọrọ mii lẹyin to sọ pe o san fun oun lai tii lọkọ bayii ju ki oun ti ṣe igbeyawo lọ.
Nkechi to sọrọ yii lori ayelujara ṣalaye pe o san fun oun ki oun ni ayọ lai tii lọkọ ju ki oun wa lọọdẹ ọkọ pẹlu inanujẹ ọkan lọ.
''Ẹyin omugọ ti ẹ n pariwo ẹnu pe ki n lọ ṣe igbeyawo, ti o ba ka yin lara, ẹ wa fi ipa mu mi ki ẹ si sin mi lọ si ile ọkọ,'' Blessing lo sọ bẹẹ.
Gbajugbaja oṣere ọhun to awọn eeyan ko mọ ẹnikan ni pato gẹgẹ bi ọrẹkunrin ṣalaye pe ko si ohun to buru ninu ki eeyan maa ti lọ sile ọkọ ni wọn igba to ba ti layọ.
Laipẹ yii ni Blessing tun sọ fawọn akọroyin pe ikebe ti Eleduwa fi jinki oun tobi ju ohun ti oun le dọwọ bo lọ.
O ni gbogbo eeyan lo mọ pe Ọlọrun pari iṣẹ si ẹyin oun, o ni awọn to ni ipenija oju kan to ba sun mọ oun le mọ bi ikebe oun ṣe tobi to.
Gbajugbaja oṣere naa ni o jẹ iyalẹnu fun oun pe awọn kan n sọ kaakiri wi pe oun maa n ju idi oun fun ṣe ki a ri mi ṣugbọn o sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Blessing ni aṣiṣe nla lawọn to n sọ pe oun ju idi kiri ki awọn aye le maa sọrọ ṣe nitori iṣu Ọlọrun ti ko ṣe fọwọ bo ni ikebe naa jẹ foun.
O tun mẹnu idi ti o fi n gbaruku ti Laycom nile Ẹlẹgbọn Agba iyẹn Big Brother Naija.
Gbajugbaja oṣere Yoruba naa ni ọlọpọ pipe ni Laycom, eyi lo jẹ ki oun maa dibo fun un.