You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kolade Johnson; Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí ọlọ́pàá tó ṣekúpaá
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko sọ pe ọwọ oun ti tẹ awọn ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o pa ọdọmọkunrin kan nilu Eko.
Ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Aje, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bala Elkana, sọ pe ẹri lati ẹnu awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn lo fun ileeṣẹ ọlọpaa ni anfaani lati da ikọ ọlọpaa to hu iwa ipaniyan naa.
Lọjọ Aiku ni iroyin gba gbogbo ori ayelujara pe awọn ọlọpaa SARS yinbọn pa ọkunrin kan, Kolade Johnson, ni agbegbe Onipẹtẹsi, Mangoro niluu Eko.
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn afurasi ọhun ti wa ni atimọle, ati pe wọn yoo fi iya to tọ jẹ wọn labẹle tabi gbe wọn lọ sile ẹjọ ti iwadi ba fi le fihan pe wọn jẹbi ẹsun naa.