You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FRSC: Ajínigbé tó kọlu òṣìṣẹ́ wá, èèyàn méjì kú, mẹ́rin farapa, a kò mọ ibí tàwọn mẹ́wàá wà
Ọrọ awọn ajinigbe loju popo Naijiria, kaka ki ewe agbọn wọn dẹ, niṣe lo n le si.
O difa fun bi wọn ṣe ṣe ikọlu sawọn oṣiṣẹ ajọ ẹsọ oju popo Naijiria, FRSC kan ti wọn rin irinajo lati ẹka ajọ naa ni Kebbi ati Sokoto wa si Udi.
A gbọ pe awọn olubi wọn yi ṣina fun awọn ẹsọ alaabo ọhun ni orita Udege loju ọna Mararaban-Udege ni ipinlẹ Nasarawa ti wọn si ji eeyan mẹwaa gbe lọ.
Ọga agba ajọ naa to n risi ọrọ idanilẹkọ ara ilu Bisi Kazeem fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan to fi sọwọ sawọn oniroyin.
Gẹgẹ bi ohun ti Kazeem sọ, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa ku ninu ikọlu yi ti omiran si gbẹmi mi ni ile iwosan.
Bẹẹ lo ṣalaye si pe awọn mẹrin mii farapa ti awọn mẹjọ ribi sa asala fun ẹmi wọn ṣugbọn awọn ajinigbepawo naa gbe awọn mẹwa salọ ninu wọn.
Ọga patapata ajọ naa Boboye Oyeyemi sọ pe awọn ti fi ọrọ yi to awọn agbofinro leti ki wọn baa le tete doola ẹmi awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn jigbe.
O ni iwadii n tẹsiwaju lati ri pe awọn to wa nidi ọrọ yi foju ba ile ẹjọ. Arakunrin Bisi Kazeem ni ọga ajọ naa ti wa rọ awọn oṣiṣẹ FRSC lati ma ṣe jẹ ki iṣẹlẹ yi mu irẹwẹsi ọkan ba wọn. Ijinigbe lawọn oju popo Naijiria ti wa peleke si lẹnu ọjọ mẹta yi ti ọpọ si ti padanu ẹmi wọn lọwọ awọn alaburu ẹda ajinigbepawo