You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Suicide Prevention Day: Wo àmì márùn-un tí o fi le mọ ẹni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀
Gbígba ẹ̀mí àra ẹni jẹ́ àrùn tó ni ṣe pẹ̀lú ọpọlọ, tí ó sì le fa ikú àìtọ́jọ́, sùgbọ́n ó ṣeeṣe kó ní àtúnṣe ti àwọn ènìyaǹ bá tètè mọ̀, tí wọ́n si ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí o bá rí ẹnìkan to n lọ lójú pópó, ó maa ròó pé sáká ni àra rẹ̀ dá, pàápàá jùlọ, tó bá ń ṣàwàdà tàbí rẹ́rìn-ín, sùgbọ́n òótọ́ ibẹ̀ ni pé, wọ́n kan ń fí ẹẹrin náà bò ìṣoro wọn mọ́lẹ̀ ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Àlàyé rèé lórí bí mo ṣe fi ọsàn híhó fẹ́ ìyàwó mi"
- Ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan ní pápákọ̀ òfurufú l‘Eko tó ń kó ike ATM 2,886 lọ si Dubai
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọba Kwara fẹ́ sọ orúkọ Rashidi Yẹkini di mánigbàgbé
- Ọ̀kẹ àìmọye ẹ̀rọ àyẹ̀wò káàdì olùdìbò jóná mọ́lé l' Ondo
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
Lọ́pọ̀ ìgbà, gbígba ẹ̀mi ara ẹni ni òpin fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ni àrun to niṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀, bí 'Bipolar', 'Depression', 'Schiophrenia' tó fi mọ́ 'Anxiety disorder'.
Bẹ́ẹ̀ àwọn ìrònú àròròtán lóri ètò ọ̀rọ̀ ajé àti ìgbéyàwó ló maa n ti ẹlòmíràn láti pa ara rẹ̀.
Dókítà Isah Shaedouw Baka, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ààrùn ọpọlọ sàlàyè pé, àwọn ènìyàn tó fẹ́ gba ẹmi ara wọ́n jẹ́ àwọn tí ọ̀rọ̀ ara wọ́n tí sú wọ́n tàbí ti inú wọ́n ba tí dùn jù lórí ǹkankan.
O ni ipele kan náà ni àwọn méjèèjì wà.
Gẹ́gẹ́ bi àjọ WHO ṣe sọ, ipò kẹẹdógún ni Nàìjíríà wà lárá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sábà máa ń gba ẹmi ara wọ́n jùlọ.
Nàìjiríà si wà ni ipò keje ní ilẹ̀ Afíríkà, Cameroon ló wà ni ipò kẹrin nígbà tí Ghana kò si ni ipò méjìlá àkọ́kọ́, nínú orílẹ̀-èdè ti àwọn ènìyàn ti n gba ẹ̀mi ara ẹni.
Sùgbọ́n kí wá ni àwọn àmìn tí wọ́n lé fi han gàn, tí ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ fi lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àwọn àmì tí o fi le mọ ẹni tó fẹ́ pokùnso:
Ẹlẹ́rìí:
Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ gba ẹmi àrà wọ́n sába máá n wa ẹlẹ́rí, láti fi àmì ìkìlọ̀ sílẹ̀, wọ́n ma a ń wá ẹni ti wọ́n yóò sọ fún pé, àwọn fẹ́ gba ẹmi ara wọ́n.
Dókítà Baka sọ pé, ẹni tó bá sọ fún ọ pé, ayé ti sú òun, lé fi ẹrin sọ ọ́ tàbi kí o léjú, sùgbọ́n àmi ńla ni pé, ó ṣeeṣe ki irú ẹni bẹ́ẹ̀ maa rònú láti pa ara rẹ̀.
Tí o bá ti ń gbọ́ tí ènìyàn ń sọ pé, "ayé ti sú mi" tabi Kí òpin ayé tíẹ̀ dá báyìí", ara àmì pé ẹni náà le gba ẹ̀mi ara ẹni ni.
O ṣe é ki ẹni náà maa sọ̀rọ̀ nípa ikú ṣaa , àwọn àmi rèé láti mọ̀ pé ẹni náà fẹ́ pa ara rẹ̀.
Dr Maynunah Kadiri, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ Pinnacle Medical Services, tó má a ń yan amójútó àwọn ìpénija tó ni nnkan ṣe pẹ̀lú ọpọlọ láàyò salaye pe,
" Ọ̀pọ̀ àwọn tó má n gbèrò láti pa ara wọn, tí o bá rí wọ́n, yóò dàbí ẹni pé wọ́n ń ṣe àwàdà ní, sùgban ti o bá tẹtí láti gbọ́ ìtàn wọn , òyé yóò ye ènìyàn láti mọ́ pé, wọ́n le pa ara wọn,"
Ó ní ọ̀pọ̀ tilẹ̀ máá n fi ìwé sílẹ̀ fún àwọn tó sún mọ́ wọ́n, láti sọ ìdí ti wọ́n fi gbé ìgbẹ́sẹ̀ náà, wọ́n le kọ̀ ọ́ pé, asán ni aye yìí, tí wọn yoo si ti fi iwé yìí sílẹ̀.
O ni eyi túmọ̀ si pé "wọ́n ti ṣetò gbogbo rẹ̀, ki wọ́n to gbé ìgbẹ́sẹ̀.
Àìní ífẹ̀ sí ǹkankan to dára mọ́:
Ní kété ti àwọn ènìyàn kò bá ti ni ìfẹ́ sí àwọn ǹkan to dára mọ́, o seese ki wọn pa ara wọn.
Tí ńkan to n lọ láyìká ẹni náà, kò bá ti ni ìtùmọ̀ si mọ́, tó kàn dà bi ẹni pe ó kàn gbe aye ṣá, o yẹ ka fura siru wọn.
Dokita ni eyi tumọ si pé, o ti ń rònú láti gba ẹ̀mí àrà rẹ̀ ni, Ounjẹ kìí wù jẹ, kò fẹ́ ni ọ̀rẹ́ tàbí alábárò, Dókìtà Baka sọ pé, ọ̀rọ̀ náà ti kọjá bẹ́ẹ̀ nìyẹn.
Àwọn ènìyàn máa n ròó pé, wọ́n sọ èyí nítorí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ kan dùn wọ́n ni, wọn ò ni mọ̀ pé wọ́n ti ni àrùn ọpọlọ.
Wọ́n má n bínú jù tàbi ki wọ́n ma bá àwọn ènìyàn ṣe mọ́.
Tí ènìyàn bá fẹ́ láti máa dáwà, kí o maa sá fún ọ̀rẹ́ tàbi àéjọ àwọn ènìyàn, èyí jẹ́ ọ̀kan gbòógí pé ìrónú tó n dàmú ọpọlọ ti ṣẹlẹ, tí ènìyàn kò bá tètè fúra, ó lè jásí kí ó gba ẹ̀mi ara rẹ̀.
Ẹlòmíràn kò ni kùrò láàrín ọ̀rẹ́, sùgban ọ̀rọ̀ ti kò tó ǹkan ni wan yóò máa fa ìbínú yọ gidi ti yóò si di ìjà ńla.
Tí ọ̀rọ̀ náà ba ti wá n ri bẹ́ẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, ẹ ó gba pé wọ́n tí gba ẹmi ara wọ́n, Dókítà Baka lo sọ bẹ́ẹ̀.
Wọ́n a maa hu àwọn ìwà to léwu:
Ìwà àwọn ti ayé bá ti sú máa n yí ìwà pada, yóò maa ṣe àwọn nńkan to le kó o sínú ewu.
O lé má a wa ọkọ̀ ni ìwàkuwa, a gbọdọ mójútó bo ti n sáré tó bá n wakọ̀ ju bi ó ṣe máa n sáré tẹ́lẹ̀ lọ, tàbi kí o maa mú ọtí àmupara tàbi ki o maa ló òògun kọja ǹkan ti wọn fún láti lòo
Ó le má a sọ̀rọ̀ àsọjù.
Ẹkún sisun
Dókìtà Kadiri ni ẹkún wọn kìí ṣe eyi ti eniyan ń sun, ti yóò simi, ẹkun asu-un-dakẹ ni.
O dá lóri iye ìgbà ti ẹni náà bá fi n sunkun, bí ẹkun naa ṣe pẹ tó, bọ́ya ẹni kan lo mú u bínú tàbi ó kàn dédé sunkún.
Kíni àwọn ǹkan ti o lè ṣe láti ran ẹni tó fẹ́ gba ẹmi ara rẹ̀ lọ́wọ́:
Ọ̀nà àkọ́kọ́ láti déna rẹ̀ láti inu ilé ni
Kọ́kọ́ gbà pé ẹni náà ni ìṣòrò tó ń kojú:
Tí o bá ti gbà pé ẹni náà ni ìṣòro, o le ràn lọ́wọ́, ti ó sì súnmọ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Jẹ́ ki wọ́n ni ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, nítorí àwọn tó ni ìṣòrò yìí kìí gbà pé àwọn ni ìṣoro, sugbọ́n ti wọn ba rí ọ bi ọ̀rẹ́ tó súnmọ́ wọn, wọ́n yoo le fi ọkàn tan ẹni náà.
Má dáwọn lẹ́bi, máa tẹti sí wọ́n:
Tétí si ǹkan ti wọ́n ń sọ, má sì dáwọ́n lẹ́bi.
Má bèèrè ìbéèrè tó pọ̀ jù, sáà má tẹti si wọn, ki o sì maa fi oye gbé ǹkan ti wọ́n n kojú.
Má wààsú fún-un:
Má sọ Ara rẹ di pásítọ̀ fún wọn.
Kìí ṣe nítorí pé wọn kìí gbàdúrà ni wọ́n ṣe nísòro, pé wọ́n tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ fún ọ, ǹkan tó dára ni gẹ́gẹ bi Dókítà Kadiri ṣe sọ.
Rànwọ́n lọ́wọ́ láti rí ìràwọ́
O kìí ṣe akọ́ṣẹ́mọ́ṣẹ́, Nítori náà, ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí akọ́ṣẹ́mọ́ṣẹ̀ onimọ nipa arun ọpọlọ ati ihuwasi ẹda, eyi tí yóò mú ọ̀rọ̀ wọ́n gbọ́.
Tani ẹni to le gba ẹmi ara rẹ?
Dokítà Kadiri sọ pé kò sí ẹni tí kò lè gbìyànjú láti gba ẹmi ara rẹ̀, ọ̀rẹ́, ẹbi, tó fi jẹ́ alájùmọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ àti ìwọ fúnra rẹ gan.
Ẹni ti èèyàn tó sún mọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú fún, ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó, ẹni to ni àìsàn kan to buru, ẹni ti iṣẹ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, tàbi tó ni ìṣòro owó ńla kan yóò fẹ́ pa ara rẹ̀.
Dókítà Baka ní àwọn to ti le ni ọgọ́ta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ náà náà le gba ẹmi ara wọn, ti wọn ba ni ìṣòro.
Láàrin àwọn ọmọ kéékèèké ti wọn n gba ẹmi ara wọn, ọ̀pọ̀ lo ni àrun ti wọ́n n pè ni "Schizopherenia"
Schizopherenia jẹ́ àìsàn to maa n jẹ́ ki ènìyàn gba ohùn ti yóò ma dá ẹni náà lẹbi fún ǹkan ti wọ́n ṣe, ohun náà a ma jẹ́ ki aye ṣú wọ́n, yóò si ma sọ pe aye ko já mọ́ ǹkankan.