Beyonce New Album: Ìyá àgbà láti Nàíjíríà ní inú òun dùn láti kọrin pẹlú Beyonce nílẹ̀ Amerika

Iya agba, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin, Mojisọla Odegbami ti ṣoju orilẹ-ede Naijiria ati ilẹ Afrika ninu awo orin tuntun ti olorin takasufe ilẹ Amerika, Beyonce ṣẹṣẹ gbe jade, to pe orukọ rẹ ni ‘Black is King’.

Arabinrin Odegbami ni o lọ si orilẹ-ede Amerika fun itoju lai mọ wi pe aye rẹ yoo yipada si rere ni oke okun.

Ọmọde olorin, FJ Akinmurele to jẹ ẹni ọdun meje, lo jẹ ki Beyonce mọ arabinrin naa ati bi o ṣe darapọ mọ ṣiṣe awo orin tuntun ti Beyonce gbe jade.

Beyonce ni awo orin naa fihan gbangba pe awọn alawọ dudu jẹ ẹya eniyan to wunilori, ti itan wọn si bu iyi kun ọmọniyan.

Ninu orin ti o pe akọle rẹ ni ''Bigger'' ni mama agba Mojisọla Odegbami ti safihan ninu fidio naa, gẹgẹ bi ọbabinrin ilẹ Afrika, to si wọ aṣo alaranbara ilẹ Yoruba, pẹlu gele lori rẹ.

Mama Odegbami lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ wi pe ọmọ ọrẹ oun ti oun de si ọdọ wọn ni Amerika lo mu oun mọ Beyonce.

Iya naa ni bi ọrọ ṣe ṣẹlẹ ni wi pe oun ni oun ma n gbe ọmọde olorin naa lọ si ibi to ti n kọ ẹkọ orin kikọ nitori ọmọde olorin naa n kopa ninu awo orin tuntun.

Iya agba, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin, Mojisọla Odegbami ni ''iya Moji'' ni awọn oṣiṣẹ Beyonce ma n pe oun, ti iya FJ si fi orukọ oun silẹ pẹlu awọn ileeṣẹ to ma n wa awọn to ni ẹbun.

Bi iya ṣe bẹrẹ si ni ya aworan pẹlu Beyonce niyẹn, amọ wọn kilọ fun un pe ko gbọdọ gbe awọn aworan naa sita afi igba ti awọn ba ṣe afilọlẹ awo orin naa.

Mama Odegbami ni inu awọn dun pupọ lati ṣoju orilẹede Naijiria ati ilẹ Afrika ni apapọ, ti o si dupẹ lọwọ ọmọ rẹ to jẹ ki oun ṣe alabapade Beyonce.