You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Domestic Chores: Ọ̀pọ̀ àbíkẹ́yìn ń bèèrè pé ṣé ègún ni láti kẹ́yìn nínú mọ̀lẹ́bí?
Se ni oju opo Twitter n gbona fẹlifẹli ni aarọ ọjọ Aiku, nigba ti ọmọbinrin kan fi ọrọ aburo rẹ, tii se abikẹyin ile wọn, to araye leti.
Gẹgẹ bi Mira Jones ti safihan lẹta kan loju opo Twitter rẹ, @mirajones, o ni abikẹyin ile awọn, Mehitabelle Jones Emmanuela lo faraya pe isẹ ile n pa oun lori lọ.
Ninu lẹta naa si ni abikẹyin naa ti gbe awọn ofin tuntun kalẹ, to si n sọ nipa awsn isẹ ile ti yoo maa se ati eyi ti yoo pa ti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Boko Haram 601 parí iléẹ̀kọ́, ìjọba yóò san ₦20,000 lóṣù fún ẹnì ìkọ̀ọ̀kan
- Aráàlú faraya torí èèyàn 63 tó dèrò ọ̀run ní Gúúṣù Kàdúná láàrin ọ̀sẹ̀ kan
- Hospital Wedding: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú
- Èèyàn 11 kú, èèyàn 438 míràn tún kó COVID-19 ní Nàìjíríà l'Ọ́jọ́ Àbámẹ́ta
- Bí o ṣe lè forúkọ silẹ̀ fún ètò "N75BN Nigerian Youth Investment Fund" rèé...
- Lizzy Anjọnrin fẹ̀si fáwọn agbọ́yì-sọ̀yí lórí ìgbéyàwó rẹ̀, Madam Sajẹ dasójú ilé iṣẹ́, àti àwọn ǹkan míràn tó ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí
Koda, gbogbo mọlẹbi rẹ ni ọmọbinrin naa darukọ lọkọọkan, to fi mọ aja wọn, to si sọ isẹ to fi silẹ fun ikọọkan wọn.
Ninu lẹta naa ni Mehitabelle ti ni abọ ti oun ati awọn obi oun nikan ba fi jẹun ni oun yoo maa fọ, koda, oun ko ni fọ ikoko ti wọn ba fi se ọbẹ abi ounjẹ rara.
Bakan naa lo ni oun yoo maa wẹ fun aja awọn, Zyron ni ọsọọsẹ, oun yoo si maa ko igbẹ rẹ pẹlu, to fi mọ titun ibugbe rẹ se.
Ọmọbinrin abikẹyin naa ni isẹ oun kọ ni titun yara igbalejo awọn se, amọ oun yoo maa tan ẹrọ amunawa wọn ni alaalẹ, ẹnikẹni ko si gbọdọ wa ji oun lati wa pa, ti oun ba ti lọ sun.
O fikun pe oun yoo maa fa omi tabi pọn omi gẹgẹ bi oun ti n se tẹlẹ, ti oun yoo si maa rọ omi sinu ike ti wọn n gbe sinu ẹrọ amomitutu.
Mehitabelle wa n gbarata pe isẹ ile ti wọn gbe le oun lori ti pọ ju, to si n beere pe se egun ni pe kii eeyan jẹ abigbẹyin ninu ile ni?
Koda, o tun fi ẹsun kan awọn ẹgbọn rẹ pe wọn roju debi pe wọn ko lee fa ina tọọṣi kuro lẹnu ina funra wọn, oun ni oun n se e.
Abikẹyin naa ni sinima nikan ni ẹgbọn oun Michelle maa n wo lọpọ igba to ba wa nile, o si kundun ko maa jade lọ.
Koda, o ni ti Ọlọrun ba fi ọwọ tọ lọkan pe ko se ounjẹ fun awọn ni ẹkọọkan, bii igba ti eeyan jẹ majele ni nitori apọju ata.
O ni yoo tun wa fi awọn ikoko to fi dana silẹ fun oun lati fọ.
Lakota, Mehitabelle wa n fewe ọmọ mọ awọn ẹgbọn rẹ leti pe gbogbo awọn lo ni aja to wa ninu ile, ojuse apapọ awọn si ni lati tọju rẹ.
Ọrọ yii si ni awọn eeyan ti n gba bii ẹni gba igba ọti loju opo Twitter, ti ọpọ abikẹyin ti ọrọ naa kan julọ, si n sọ awọn iriri tiwọn naa, eyi to pa ni lẹrin pupọ.