Coronavirus: Ọ̀rá ni àwọn dókítà fi ń dáàbò bo ara wọn nílẹ̀ẹ Gẹ̀ẹ́sì

Bi iye awọn eeyan to ti gbẹmi mi nitori Coronavirus ṣe n peleke sii nilẹ Gẹẹsi, bẹ naa ni awọn ile iwosan atawọn oṣiṣẹ eto ilera n wa ọna lati koju arun ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe wọn dẹkun wọn lati ba ileeṣẹ iroyin sọrọ, ọpọ awọn oṣiṣẹ eto ilera nilẹ Gẹẹsi ti sọ ẹdun ọkan wọn fun ileeṣẹ iroyin BBC nipa bi aini irinṣẹ to peye ṣe n jẹ wọn niya.

Ọkan lara awọn dokita ilẹ naa, Roberts sọ pe ile iwosan ti kun fun awọn alaisan Coronavirus.

O ni awọn nọọsi to wa nilẹ ko to fun iye awọn alaisan to nilo itọju, bẹẹ naa ni ko si ogun ati awọn ibusun ti alaisan le fẹyinle. Ṣugbọn o jẹ ohun iyalẹnu pe ọra lasan ni awọn to n ṣeṭoju alaisan fi n dabo bo ara wọn, fun nnkan bi wakati mẹtala ti wọn n lo lẹnu iṣẹ.

Dokita ọhun ni ijọba gba awọn ara ilu lati jinna rere si ẹni ti wọn ba funra sip e o ni arun Coronavirus lara, ṣugbọn awọn to n ṣiṣẹ nile iwosan n fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu alarun naa laisi ohun idabo bo ara ẹni to kun oju oṣuwọn.

O tẹsiwaju pe ọpọ oṣiṣẹ ni awọn ẹka ile iwosan rẹ lo wa ninu ibeorubojo nitori wọn ko mọ iru aisan to le kolu wọn lọjọ iwaju.

Roberts fẹsun kan ijọba pe ko pese ohun to yẹ fun awọn oṣiṣẹ ile iwosan rẹ, idi ree ti wọn ṣe n lo ọra lati fi dabo ara wọn, eyi ti ko bojumu.Ṣaaju ni ijọba ilẹ Gẹẹsi ti sọ pe oun n ni idojukọ pẹlu pinpin awọn ohun elo idabobo ara ẹni ọhun, ṣugbọn iṣẹ n lọ pẹlu ifọwosoẉọpọ awọn ọwọn ọmọ ogun lati ri pe ohun elo naa kari.Ijọba ni iboju ti ko din ni miliọnu kan ni oun ti pin si awọn ile iwosan ni ọjọ kinni oṣu kẹrin ọdun 2020, ṣugbọn dokita Robert sọ pe ọrọ ko ri bẹ nitori ile iwosan ohun ko ri ohunkohun gba.

O ni "Iboju to wa lọdọ wa bayii yẹ ko ti pari iṣẹ lati ọdun 2009, awọn kan yẹ ko ti pari iṣẹ lati 2013, ti awọn toku yoo kọṣẹ lọdun 2021, gẹgẹ bi akọle to wa lara rẹ."Dikita naa pari ọrọ pe ki awọn ara ilu joko sile wọn lọna ati dabo bo ara wọn ati awọn ololufẹ wọn.