Coronvirus in Nigeria: Àjọ NCDC ti kede pé ènìyàn méji míran ti ni àrun náà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ní ìròlẹ́ òní ni àjọ to n ri si itankalẹ ajàkálẹ̀ àrun ti tún kéde pé ènìyàn méji míràn tú ti kú àwọn méjilelogoji to wà nilẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti o si ti di ẹni mérinlélógójì báyìí to to ti ni ààrun náà ni Naijira.

Awọn méji oun ti rín irin ajò lọ si olrilẹ̀-èdè UK àti Germany, súgbọ̀n kìí se ilú Eko ni wọ́n de si báyìí.

Awọn méjèèjì náà ni wọ́n ri ọkan ni Abuja nígba ti okán wà ni Bauchi

Ní dede ààgo mẹfa kọjá iṣẹju mẹẹdọgbọ̀n ni NCDC kédé ènìyàn méji túntun náà

102,000 ènìyàn jàjàbọ́ lọ́wọ́ COVID-19 lágbàáyé

coronvirus world: 102,000 ènìyàn jàjàbọ́ lọ́wọ́ COVID-19 lágbàáyé

Fasiti iwadii ti John Hopkins to ni Baltimore ni Maryland lorilẹ-ede America ti fi abajade akọsilẹ iṣẹlẹ corona virus lagbaye ti wọn ṣe sita.

Abọ akọsilẹ naa fihan pe awọn to ti bọ lọwọ aarun coronavirus ti tun pọ sii lagbaye.

Bayii coronavirus ti de orilẹ-ede mẹwaa din ni igba ni gbogbo agbaye.

O ti le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun awọn eniyan ti wọn ti kagbako Coronavirus yatọ si China nibi to ti kókó bẹ silẹ.

Ninu awọn eniyan 382, 000 to ti lugbadi aarun yii, awọn eniyan 102, 000 ni akọsilẹ fasiti yii fidiẹ mulẹ pe wọn ti gbadun tan patpata bayii.

Awọn eniyan 16, 600 ni wọn ni wọn ti di oloogbe bayii.

Bo tilẹ jẹ pe awọn miran n ku lataari awọn aisan to ti wa lara wọn tẹlẹ.

Abba Kyari lùgbàdì aàrùn coronavirus- Reuters

Coronavirus in Nigeria: Èèyàn mẹ́rin míì kó coronavirus ní Nàìjíríà, ogójì ló ti di níi báyìí

Iroyin ti Reuters fi lede ni Ogbẹni Abba Kyari to jẹ awọn oṣiṣẹ nile ijọba apapọ ni Aso Rock nilu Abuja ti lugbadi aarun coronavirus.

Eni kan to ba wa sọrọ to jẹ ogbontarigi nile ijọba ti ko fẹ ki wọn darukọ oun fidiẹ mulẹ fun BBC pe otitọ ni iroyin naa.

Ṣaaju nigba ti iroyin yii bẹrẹ si ni tan kalẹ ni BBC kan si olubadamọran Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu ko le fiidi ọrọ na mulẹ tabi bẹẹkọ.

Gbogbo igbiyanju BBC lati gbọ ohun to n ṣẹlẹ bayii lẹnu Garba Shehu lo ja si pabo.

Reuters ni Abba Kyari rinrin ajo lọ si orilẹ-ede Germany nibẹrẹ oṣu yii pẹlu ikọ awọn oṣiṣẹ ijọba kan lati ṣe ipade pẹlu Siemes.

Reuters ni awọn ko le sọ igbesẹ ti Abba Kyari tabi ileeṣẹ ijọba apapọ n gbe bayii.

Eni mẹ́rin míì kó coronavirus ní Nàìjíríà, àfàìmọ̀ kó má dàbi ti China, Italy- Mínísítà kìlọ̀

Ajọ NCDC ṣalaye pe mẹta ninu awọn eeyan wa lati ipinlẹ Eko nigba ti ẹyọkan to ku wa lati olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

O ti di ogoji eeyan to ti lugbadi arun coronavirus bayii lorilẹ-ede Naijiria, lẹyin ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC kede awọn mẹrin mii to ti ni aisan naa lalẹ ọjọ Aje.

Ajọ NCDC ṣalaye pe mẹta ninu awọn eeyan wa lati ipinlẹ Eko nigba ti ẹyọkan to ku wa lati olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

NCDC ni awọn meji ninu wọn ṣẹṣẹ rinrin ajo de lati oke okun ni.

Gẹgẹ bi alaye ajọ NCDC loju opo Twitter rẹ, eeyan meji ninu awọn ogoji eeyan to lugbadi arun Covid-19 ni Naijiria ti kuro nile iwosan.

Eeyan ti dero ọrun ninu awọn to larun naa ni Naijiria, ọjọ Aje ni ọkunrin naa ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ku.

Ohun ti a gbọ ni pe ọkunrin ti ni arun itọ ṣuga ati arun jẹjẹrẹ lara tẹlẹ ki o to lugbadi coronavirus.

Ni bayii, eeyan mejidinlọgọn lo wa lati ipinlẹ Eko ninu ogoji to larun naa ni Naijiria, meje lati Abuja.

Eeyan meji wa lati ipinlẹ Ogun, nigba ti ipinlẹ Ekiti, Oyo ati Edo ni ẹyọ kọọkan.

Ẹwẹ, minisita fun eto ilera, Dokita Osagie Ehanire ti sọ pe afaimọ ki ọrọ Naijiria naa ko ma dabi ti orilẹede China ati Italy lori bi ọrọ coronavirus ṣe n lọ yii.

Minisita ọpọ ọmọ Naijiria to ni arun coronavirus ni wọn n deju mọle, dipo ki wọn jade fun itọju ki arun naa maa ba ran awọn mii.