You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Emir of Kano: Sanusi ní òun mọ ohun tí òun leè ṣe láti gba ipò Emir òun padà
Emir ilu Kano tẹlẹ, Lamido Sanusi ti ni oun mọ ohun to yẹ lati ṣe, ti oun ba fẹ pada si ipo Emir ilu Kano.
Sanusi de ilu Eko lọjọ Ẹti lẹyin ti ileẹjọ kan niluu Abuja paṣẹ pe, ki ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi silẹ lahamọ to wa niluu Awe nipinlẹ Nasarawa, lẹyin irọloye rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Emir ana naa ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Kano ko tẹle ilana to tọ lati rọ oun loye.
Sanusi to jẹ ọga agba banki apapọ orilẹede Naijiria tẹlẹ sọ ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa pe, iwe irọniloye oun ti ijọba kọ ku diẹ kaato, o ni o rọrun fun oun lati tako igbesẹ ijọba nileẹjọ.
Amọ, Sanusi ni ọrọ oye Emir ilu Kano ti di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ fun oun, o ni oun ti ṣe iṣẹ ti oun fẹ se tan laarin ọdun mẹfa ti oun lo gẹgẹ bi Emir ilu Kano.
Emir ilu Kano tẹlẹ ni ohun ti ileẹjọ yoo beere ni boya ijọba ti ṣe ikilọ fun oun tẹlẹ, ko to yọ oun nipo, tabi ṣe wọn ti gbọ tẹnu oun.
Ṣugbọn Sanusi ṣalaye pe, ipele tuntun lo kan bayii ninu irin-ajo oun, nitorinaa oun ko raye lati maa lọ si ile ẹjọ lori ati pada si ipo Emir ilu Kano.
O fikun ọrọ rẹ pe, iyọnipo oun kii ṣe ohun to le jọ ki inu oun bajẹ nitori oun ko rii bẹẹ rara.