You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Wale Akintade ní ìjọba ń sanwó oṣù fáwọn àmọ́ nǹkan kò rọgbọ
Àìsàn Coronavirus to n jagún káàkiri agbáye ko ti sinmi ìjà rẹ, se lo si n ja rain lọ gẹgẹ bii ajakalẹ arun ti wọn pe e.
Bí gbogbo ènìyàn ṣe n lọgun pe, sebi ilú Wuhan ní China ni arun Coronavirus ti bẹ̀rẹ̀, sùgban báwo lo ṣe wá jẹ pé orilẹ̀-èdè Italy lo n pín ààrùn náà kiri laarin àwọn orilẹ̀-èdè to ko arun ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Pẹ̀lú gbogbo ìròyìn ajanilaya to n waye lati Italy nipa ọsẹ arun Coronavirus naa, lo mu ki BBC Yoruba kàn si àwọn ọmọ Naijiria to wà lorilẹede naa, láti mọ irú ipò ti wọ́n wà pẹ̀lú ajakálẹ̀ ààrun yìí.
Ọkan nínú àwọn to bá BBC sọ̀rọ̀, Wale Akintade sàlàye pé, aláfíà ni àwọn wà bo tilẹ̀ jẹ́ pé ààrun náà n bá àwọn ènìyàn Italy fira gidigidi, o ni ko kan àwọn alawọ dúdú to wa nibẹ, àwọn ọmọ ilẹ Italy àti àwọn ọmọ China ni ọ̀rọ̀ náà kan jùlọ.
Akintade ni ìròyìn ti àwọn n gbọ ni pe, àwọn ènìyàn dudu ti Coronavirus mu kò ju bii mẹta lọ, sùgbọ́n yàtọ si ààrun náà, ǹkan ko rọ̀gbọ fun ẹnikẹni nitori wọ́n ti dènà mọ gbogbo ǹkan.
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
- Eré apanilẹ́rìn ké kè ké lórí ayélujára ti ṣí ọ̀pọ̀ ìlẹ̀kùn fún mi - Mr Macaroni
- Chatta bímọ tuntun, Mide àti Osupa lẹ̀pọ̀, Sanwo-Olu fún Sola Sobowale lámì ẹ̀yẹ
- Osinbajo wọ́gilé ìrìn-àjò rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ kú nínú ìjàmbá ọkọ̀
Okúnrin náà fi kún pé, àti ọkọ̀ ofurufu, àti reluwe ni wọn ti tì pà, káràkáta náà ti dẹnu kọlẹ, ko si si ẹni to le wọle láti ilẹ̀ okere rara, konile o gbéle ni gbogbo ènìyàn wà.
O ni adura ti àwọn kan n gbà ni pe, ki arun naa ma ran àwọn ènìyàn dúdú, o ni ilé ìwòsàn, ilé oogun àti ile itaja ìgbàlode nikan ni wọ́n gba láti ṣilẹkun wọn.
Akintade fikun pe bo tilẹ̀ jẹ́ pe àwọn ko ṣiṣẹ́, síbẹ̀ ijọba n san owó fawọn laiyinjẹ ti oṣù bá ti pari, eyi ti ko jọ ohun to n waye nilẹ Afirika to jẹ pe ẹni to sisẹ gan ko ri owo osu rẹ gba.
Ní ojúmọ to mọ lónìí yìí, ènìyàn to lé ni ẹgbẹ̀run lọ́na mẹ́tàdinlógun lo ti ni ààrun náà, èníyan to le ni ẹgbẹ̀fà lo si ti ba iṣẹ̀lẹ̀ náà lọ nígbà ti ènìyàn ẹgbẹ̀run kan o lé márundinláàdọta rú ààrun náà là, ti wọn si pada si ilé wọ́n.