Buhari Ataack: Lai Muhammed ní Jamil yóò wá sílé ìjọba láti bọ ààrẹ lọ́wọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Arakunrin Mohammed Jemilu, ti fidio rẹ́ gba ori ayelujara kan pe o fẹ́ pa aarẹ́ wa, Muhammadu Buhari ti sọ̀rọ̀ sita.

Jemilu , lasiko to n ba awọn onirioyin sọrọ ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti awọn eniyan kan n sọ wi pe, ẹsọ alaabo Aarẹ Buhari yin ibọn mọ oun lasiko ti oun ku giri mọ̀ aarẹ ni Ọjọbọ ni ipinlẹ̀ Kebbi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jemiu lasiko to sọ́rọ ni ilu Birnin Kebii ni Ọjọ Ẹti ni ẹni ọgbọn ọdun ni oun, ti oun si kẹkọ jade lati ileewe giga fasiti ti Usman Dan Fodio ni ipinlẹ Sokoto, nibi to ti kẹkọ gboye imọ sayẹnsi.

O ni ifẹ ti oun ni si aarẹ Buhari lo mu oun gbe igbeṣẹ yii laki tara kii, kii si se pe oun fẹ se aarẹ Buhari ni ijamba.

"Iwuri lo jẹ fun mi bi mo ṣe ri aarẹ Buhari nitori o jẹ olooto si mi, ati ẹni to fẹran orilẹede Naijiria fun idagbasoke to muna doko."

Ninu ọrọ rẹ, O ni aarẹ Buhari n lo awọn ohun alumọni Naijiria daradara lai ko owo ẹnikẹni jẹ, afi ko ṣiṣẹ takuntakun.

"Nigba ti mo ri aarẹ, mo gbagbe gbogbo awọn to duro ti i, ohun to wu mi ni lati fi ọwọ kan an, mi o kọ ki n ku nitori mo fẹran aarẹ Buhari."

Lasiko to n fesi si ọrọ rẹ, minisita fun eto iroyin ati asa, Alhaji Lai Muhammed sọ wi pe, iṣẹlẹ naa nii se pẹlu titẹ ilana eto aabo aarẹ Niajiria loju.

Bakan naa lo ni oun yoo ri daju pe, Jemilu yoo ṣe abẹwo si aarẹ Buhari ni ile ijọba ni Abuja, ki o ba le bọwọ aarẹ Buhari.

Amọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ wi pe, ijọba gbọdọ ṣe iwadii iṣẹlẹ naa finifini, lọna ati ri pe awọn eniyan ko dede lanfaani si aarẹ, lai si wi pe o mọ tẹlẹ ri.