Facebook love: Ọla àti Folashade pàdé ni Facebook, wọ́n ṣègbéyàwó lẹ́yìn ọjọ́ mọ́kànlá tí wọ́n ríra
O ti pẹ ti a ti n ri ajọṣepọ ifẹ laarin awọn eeyan lori ikanni ayelujara Facebook, ṣugbọn lọpọ igba ni irufẹ ajọṣepọ bẹẹ maa n ja si okolobo.
Sibẹ, a tun n ri iwọn ninu rẹ ti o n de ibode alayọ nibi ti awọn mejeeji tọrọ kan maa n pada wa di lọkọ laya.
Itan Ọlaoluwa Fọlaṣade niyi, wọn ri ara wọn lori Facebook, lẹyin ọjọ mọkanla wọn ṣe igbeyawo
Igbeyawo to jẹ akanṣe ni eyi. Ogoji eeyan pere ni wọn pe, o si larinrin.