Joseph Yobo ni igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tuntun - NFF

Ajọ to n ri si ọrọ ere bọọlu ni Naijiria, NFF ti kede Joseph Yobo gẹgẹ bi igbakeji akọnimọgba ikọ naa tuntun.

Yobo bọ si ipo yii lẹyin ti wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Imama Amapakabo to di ipo na mu tẹlẹ.

Ki Yobo to de ipo tuntun yii, o ti fi igba kan jẹ balogun ikọ Super Eagles to si ṣe aṣeyọri ninu idijẹ ifẹ ẹye ti ilẹ Afrika to waye lọdun 2013.

Yobo ni ọpọ iriri gẹgẹ agbabọọlu latari bo ṣe ti gba bọọlu ni oriṣiriṣi ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri agbaye.

O gba igbega si ikọ Super Eagles lẹyin to ṣoju orilẹ-ede Naijiria ninu idije ọjẹ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ti ju ogun ọdun lọ lọdun 1999.

Ko ti di pe Yobo fẹyinti gẹgẹ agbalọọlu fun ikọ Super Eagles, o ti kopa ninu idioje ife ẹyẹ agbaye nigba mẹta, ati ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika nigba mẹfa.

Lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti Yobo ti ṣeṣẹ tẹle ni ikọ Olympique Marseille, Everton, Norwich City ati Fenerbahçe.