Victor Olaiya: Ẹni ọdún 89 ni àgbà olórin tó jáde láyé!

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Victor Abimbola Olaiya ti gbogbo eniyan mọ si Victor Olaiya ti jade laye ni ẹni ọdun mọkandinlọgọrin.

Baba Victor Olaiya jẹ gbajugbaja onifere ti o ma n korin igbalode, iyẹn highlife.

Bi o tilẹ ṣepe Victor Olaiya gbajugbaja ni orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ọkan gboogi lara awọn olorin ni Naijiria.

Ọjọ Kejila, Osu Keji, ọdun 2020 ni arakunrin naa jade laye lẹyin aisan ranpẹ ni ile iwosan ikọni ti ipinlẹ Eko.

Tani ilumọọka olorin Victor Olaiya?

  • Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Kejila ọdun 1930 ni wọn bi dokita Victor Olaiya ni ilu Calabar, ni ipinlẹ Cross River.
  • Ohun ni ogunjọ ọmọ ninu ọmọ mẹrinlelogun ti baba rẹ bi.
  • Ilu Ijesha-Ishu ni ipinlẹ Ekiti ni baba ati iya rẹ ti wa.
  • Idile olowo ni Olaiya ti wa, ile wọn duro gbagiri ni ilu Eko ni agbeegbe Bamgbose, ki wọn to wo o palẹ ni ọdun 2016.
  • Lti kekere ni Olaiya ti n fọn fere, ti o si lọ si ile iwe giga lati lọ kọ̀ ẹkọ nipà orin kikọ, eleyii ti awọn ẹbi rẹ lodi si.
  • Baba Olaiya kọrin pẹlu ẹgbẹ akọrin Sammy Akpatot, oun si ni olori ẹgbẹ akọrin Old Lagos City Orchestra, lẹyin naa lo darapọ mọ Bobby Benson ati Jam Session Orchestra.
  • Baba Olaiya fi igba jẹ Aarẹ ẹgbẹ awọn olorin ni Naijiria.
  • Oni iyawo pupo ni Olaiya, to si ni ọmọ ati ọmọ-ọmọ. Lara ọmọ rẹ ni gbajugbaja oṣere Moji Olaiya to jade laye ni ọdun 2017, ti o si kọrin pẹlu mọ rẹ Bayode Olaiya.
  • Olaiya nigba aye rẹ ba olorin, ọmọ ilẹ Ghana, E.T. Mensah, Tony Allen ati Fela Kuti kọrin.
  • Ni Osu Keje, ọdun 2013 ni Victor Olaiya kọrin pẹlu 2face idibia, ninu awo orin rẹ Baby Jowo(Baby Mi Da).
  • Lara awọn awo orin ti Olaiya kọ ko to jade laye ni Odale Ore b/w Mofe Muyon,Oruku Tiniditindi / Iye Jemila,Baby Jowo(Baby Mi Da), Pambotoriboto b/w Moonlight Highlife,Feso J'aiye / Asian Udo, Kosowo Lode b/w Ewelewekuewele,Ilu Le O (Country Hard 0!) ati bẹẹ lọ.

Kini awọn eniyan n sọ nipa oloogbe Victor Olaiya?

Ọpọlọpọ awọn ololufẹ agbaọjẹ olorin, Victor Olaiya lo n ba ebi ati ara oloogbe naa kẹdun lẹyin to jade laye.

Lori oju opo ikansiraẹni Twitter ni awn ololufẹ olorin oun ti n ranti gbogbo ipa ribiribi to ko fun igbelaruge asa, ede ati orin ni orilẹede Naijiria ati Ilẹ adunlawọ lapaapọ.

Bakan naa ni awọn ololufẹ rẹ wa gbadura fun ẹbi, ara ati ọrẹ ti o fi silẹ si aye lo.