Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Àkọlé fídíò, Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Ọpọ dukia lo ti ṣofo ti ọmọkunrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan si padanu ẹmi rẹ ninu iṣẹlẹ ina to jo ni ọja Akesan nilu Oyo.

Mojumọ ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ karun un, oṣu kini ọdun 2020 ni iṣẹlẹ yi waye.

Nigba ti o n fi idi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ BBC, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo, SP Fadeyi Olugbenga sọ pe ni nkan bi aago meji oru ni ina naa bẹrẹ.