Ile Arugbo Saraki: Ìjọba AbdulRazaq ti wólé aláànúú wa ní Ilorin
Awọn eeyan to jẹ awọn alatilẹyin Bukola Saraki tu itọ soke foju gba a lori bi ijọba ipinlẹ Kwara ṣe wo ilu Arugbo lulẹ laarọ Ọjọbọ niluu Ilorin.
Awọn eeyan naa ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ko laṣẹ lati wo ile ọhun nitori ọrọ ile naa wa nile ẹjọ.
Amọ ijọba sọ pe ọna aitọ ni Oloye Sola Saraki fi gba ilẹ naa nigba naa nitori ko si akọsilẹ kankan to ṣafihan pe o sanwo fun ijọba.
- A gbẹ́sẹ̀ lé ilé kan tó jẹ́ ti Bukola Saraki, torí àpò ìjọba ló ti mú owó sanwó ilẹ̀ - Ilé aṣòfin
- Saraki: Ìwà àrékérekè ni ilé mi tí EFCC tì pa
- Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
- Ẹ̀yin ọ̀tá mi, ẹ lọ dì mọ́ òpò ina lọ́dún 2020- Ayodele Fayose
- Ó ti tán fún mí lọ́dún 2023- Ààrẹ Muhammadu Buhari
Wọn ni ijọba to wa lode nipinlẹ Kwara n fi ibi su oloore pẹlu bi o ṣe wo ile arugbo lulẹ.