Muhammadu Buhari: Olubunmi-Okogie ní Nàìjíríà ti padà s'áyé ìjọba ológun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ ajọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi, CAN tẹlẹ ri, Cardinal Anthony Olubunmi-Okogie sọ pe orilẹede ti n pada si aye ijọba ologun diẹdiẹ labẹ iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari.

Cardinal Olubunmi-Okogie bu ẹnu atẹ lu aibọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ labẹ ijọba Aarẹ Buhari.

Ojiṣẹ Ọlọrun Olubunmi-Okogie sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita, eleyi to pe akori rẹ ni ''Iwa ibajẹ ati ifagbaratẹtọẹnimọlẹ.''

'Ohun to ṣeni laanu ni pe lorilẹede Naijiria ni pe awọn olori jina si awọn eeyan ti wọn n ṣejọba le lori,' Cardinal Olubunmi-Okogie lo woye bẹẹ.

O ṣalaye pe awọn araalu lo dibo yan awọn to n ṣejọba, o ni idi niyii ti wọn fi gbọdọ maa tẹti gbọ ohun tawọn araalu n sọ.

Ojiṣẹ Ọlọrun Olubunmi-Okogie ni ti ijọba ba kọ lati paṣẹ ile ẹjọ mọ, ti o si n dunkoko mọ ẹka eto idajọ, ajẹ wi pe Naijiria ti pada si aye ijọba ologun niyẹn nigba tawọn ologun n ṣe ohun to wu wọn.

O ni laye ologun ni ijọba kan le ṣadeede ju awọn eeyan satimọle lainidi kan pato.

Cardinal Olubunmi-Okogie ni ọmọ Naijiria ko fẹ ijọba ologun mọ nitori o ti ṣakoba nla fun orilẹede yii.

Olubunmi-Okogie ni iru awọn iwa oloṣelu to fa ogun abẹle ni Naijiria bi aadọta ọdun sẹyin ni ijọba to wa lode n wu.

O ni ijọba awarawa Naijiria wa ninu ewu nitori iwa ibajẹ ati tani yoo mu mi.