You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akure Kidnap: Àwọn Abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wọ́n jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ
Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ti gbé Pasitọ ìjọ tí wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó mọ̀ sí Gold Kolawole tó sọnù ni Akurẹ
Lẹyin ifẹhonuhan ẹgbẹ awọn obinrin ni Akurẹ ni ana ni iṣẹlẹ miran tun ṣẹlẹ.
Awọn ẹgbẹ obinrin NCWS lo ṣe ifẹhonuhan lanaa ti wọn ke pe ijọba lati gbe igbesẹ to yẹ lori iwadii Gold Kolawole, ọmọdekunrin to dawati ninu ijọ Sotitọ bire Miracle Center.
Ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo ni iṣẹlẹ yii ti n ṣẹlẹ to n bi Ige ati Adubi bayii.
Arabinrin JayeOba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ loju rẹ ni aago marun un abọ irọlẹ ana ṣalaye fun akọroyin BBC to lọ sibẹ pe mọto akeru Hilux mẹfa ni ajọ DSS gbe wa.
Bakan naa ni ìya Gold Kolawole sọ fun akọroyin BBC pe inu oun dun fun igbesẹ tuntun yii pe oun mọ pe aṣiri ibi ti ọmọ oun wa a to tu.
Awọn ara adugbo naa sọ fun akọroyin BBC pe ilé pasitọ naa ni adugbo Ọ̀dá ni Akurẹ ni wọn ti kọkọ lọ gbe e ki wọn to gbe e wa si ile ijọsin naa ni adugbo Ọshinlẹ.
Wọn ni awọn DSS naa to ogun ni iye ti wọn si wọnu ile ijọsin naa lọ lasiko isin irọle aarin ọsẹ to n lọ lọwọ.
Iya Gold fi idunnu han pe pẹlu igbese yii ti wọn ni wọn ti gbe Pasitọ ti wọn n fẹsun kan pe o mọ nipa iṣẹlẹ naa lọ si Abuja fun ifọrọwanilẹnuwo yii a bi eso rere lori omọ oun Gold.
Ìjọba, ẹ bá wa wa Gold Kolawole tó dàwátì nílé ìjọsìn Akure- Ẹgbẹ́ Obìnrin
A kọ láti fi ibanujẹ ṣodun nitori Gold- Ẹgbẹ obinrin
Ẹgbẹ́ obìnrin (NCWS) ẹ̀ká ìpínlẹ̀ Ondo fárigá lórí ohun tó n ṣẹlẹ̀ nípa Gold tí wọ́n jí gbé, wọ́n bẹ Akeredolu kó bá wọn dá síi.
Lati ibẹrẹ oṣu kọkanla ni iya ati baba Kolawole Gold, ọmọ kekere ti wọn ji gbe nile ijosin ni Akure ti n ke gbajare pe ki aye ran wọn lọwọ ba wọn wa ọmọ wọn sita.
Won fẹsun kan adari ijọ ti wọn n lọ pe o lọwọ ninu ọrọ naa "Àwọn tó jí ọmọ mi gbé nílé ìjọsìn ní ń kò gbọdọ̀ wa tàbí kí ẹ̀mí mi lọ si".
Lẹyin eyi ni Oba Deji atawọn agbofinro ti gbe igbesẹ loriṣiiriṣii ni ibẹrẹ ọrọ wiwa ọmọdekunrin yii Missing Child: Òbí àti asọ́nà ṣọ́ọ̀ṣì 14, lọ́ búra nì'dí imọlẹ̀ l'Akure.
Bayii, o ti wa le ni oṣu kan ti Gold Kolawole, déedé di awati ni ile ijọsin kan ti a mọ si Sotitobire Prayer Centre, ni ilu Akure.
Gbogbo igbiyanju obi ọmọ naa lati ri i lo jasi pabo ti awọn agbofinro ko si ti i ri ọmo ọhun.
Idi eyi lo mu ki agbarijọpọ awọn obinrin kan ni ilu Akure ṣe iwọde lọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ Kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2019Àwọn abiyamọ figbe ta lórí ọmọ ọdún kan ti wọn wá nílé ìjọsìn l'Akure.
Iya ọmọ to sọnu yii lo sunkun lọ si ọdọ awọn abiyamọ pe ki wọn ba oun bẹ ijọba lati ran oun lọwọ lori ọrọ ọmọ yii.
Eyi lo ṣokunfa iwọde ẹgbẹ obinrin pe ki ijọba ati agbofinro ṣe iṣẹ wọn bi o ti yẹ.
Awọn obinrin to jade ni ko dara ki abiyamọ fi ibanujẹ ṣe ọdun keresimesi to m bọ lọna, ki Aye ba wọn da si ọrọ riri ọmọ naa, Gold Kolawole.
Arabinrin Jumoke Aborode to jẹ alaga ẹgbẹ National Council for Women Society of Nigeria, ẹka ipinlẹ Ondo ni ko si abiyamọ to fẹ foju sunkun ọmọ