You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Polio: Bàbá kọ abẹ́rẹ́ àjẹsára kí ọmọ rẹ̀ tó ní àìsàn polio!
Awọn osisẹ eleto ilera ti ni awọn ni abẹrẹ ajẹsara to le tọju awọn ọmọde kaakiri Naijiria, amọ awọn obi miran si n kọ fun ọmọ wọn lati gba ajẹsara.
Eyi ni iriri Arakunrin Adamu Misa lati ipinlẹ Yola, ni ẹkun Ariwa orilẹ-ede Naijiria.
Misa sọ nipa bii oun se tako lilo abẹrẹ ajẹsara fun gbogbo ọmọ ti oun bi, ko to di pe ọmọ oun kẹta wa ni arun polio, ti o si rọ apa ati ẹsẹ rẹ.
Adamu ṣalaye fun Charles, akọroyin BBC pe: Ọmọ rẹ, ọdun mẹjọ lo sun lai si nkan to ṣe e, ki o to wa dii wi pe ko le e gbe apa gbe ẹsẹ ati apa rẹ, ki o to di wi pe wọn gbe e lọ si ile iwosan.
Adamu ti wa di eni to n gba awon eniyan ni iyanju lati ma a gba abẹrẹ ajesara ni igbakugba fun awon ọmọ won lati dena aarun to le gba ẹmi wọn.
Ki o to di asiko yii, awọn ara agbegbe naa gbagbọ pe ti awọn ba gba abẹrẹ ajẹsara fun ọmọ wọn, awọn oyinbo naa n gba nkankan ninu ẹjẹ ati egungun awọn ọmọ wọn ni.
Ajọ ilera ni agbaye, WHO ni orilẹ-ede Naijiria ko i tii lugbadi aisan polio lati ọdun mẹta sẹyin.
Ni eyi ti o si seese ki wọn sọ wi pe Naijiria ko le e gburọ aisan polio mọ ti ko ba si iru aisan naa mọ titi di ọdun 2020.
Amọ ajọ naa n woye wi pe pẹlu ikọlu Boko Haram ni awọn agbegbe ẹkun Ariwa Naijiria, eleyii ti o le fa ki o ma si imọtoto ni agbegbe naa, o seese ki aisan naa pada.
Ajọ WHO naa wa rọ awọn obi lati ma a fun awọn ọmọ wọn ni abẹrẹ ajẹsara ti o ba yẹ nigba kugba, ki o ba le dena aarun ati iku ọmọde lorilẹ-ede Naijiria.
Ọpọlọpọ iwadii lo ti fihan pé ọmọ ti ko ba gba abẹrẹ ajẹsara lasiko to yẹ ko gbaa le pada lugbadi arun rọparọsẹ ati awọn ikọlu miran lọjọ iwaju.