You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bayelsa Election: Ilé ẹjọ kòtẹ́milọ́rùn ti pàsẹ pe'APC díje
Ilé ẹjọ kò tẹmílọrun ní ìlú Abuja tí fún APC ní iwé to wọ́gile ìdájọ ilé ẹjọ ta gá jùlọ titi tí ilé ẹjọ yóò fí gbọ́ ẹjọ wà ni ìwáju rẹ̀.
Eyí túmọ sí pé aṣẹ ilé ejọ ti Jane Inyang gbe jáde to ni pé APC ko le díje nínú ìdìbò gómínà ti yóò wáye lọ́jọ́ Satide to n bọ kò ni fẹsẹ̀ múlẹ.
Ní báyìí, ajọ eletò ìdìbò le tẹ̀síwájú láti fi olùdíje APC sinú idìbò náà titi ti ilé ẹjọ kò tẹmilọ́run yóò fi gbọ́ ẹjọ náà.
A fẹ́ gba àṣẹ míì láti takò ìdájọ́ tó wọ́gilé olùdíje wa fún ìbò gómìnà Bayelsa - APC
Ẹgbẹ oselu APC ti kede pe oun tako idajọ ileejọ giga kan to kalẹ si ilu Yenegoa nipinlẹ Bayelsa eyi to wọgile oludije fun ibo gomina ti ẹgbẹ oselu APC fa kalẹ nipinlẹ naa.
Laarọ yii ni ileejọ naa, ti adajọ Jane Inyang dari rẹ, kede pe ẹgbẹ oselu APC ko ni oludije kankan mọ ninu ibo gomina ti yoo waye lọjọ Kẹrindinlogun osu Kọkanla ọdun yii, eyiun ọjọ Satide ọtunla.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "$2,600 àǹtí mi ni mo jí láti lọ sókè òkun àmọ́ àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ mi"
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù
- Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje Sweden
- Èèyàn mẹ́tàlá dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ lópòpónà Ìbàdàn s'ÈKó
- Zlatan: Èyí mo ṣé tó, àsìkò tó láti tèsíwájú nínú ìrìnàjò mi
Amọ nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja, ẹgbẹ oselu APC kede pe oun yoo tako idajọ naa nile ẹjọ Kotẹmilọrun, ti awọn agbẹjọro oun si ti n sisẹ lati lọ gba asẹ ti yoo tun kede pe ki gbogbo igun ti ọrọ kan duro na lori idajọ ọhun.
Ìbò gómìná Bayelsa ku ọjọ́ méjì, Iléejọ́ yẹ àga mọ́ olùdíje APC ńídìí
Saaju la ti mu iroyin wa pe, ileẹjọ giga ijọba apapọ to n joko nilu Yenegoa nipinlẹ Bayelsa ti kede pe ẹgbẹ oselu APC ko ni oludije kankan mọ ninu ibo gomina ti yoo waye lọjọ Kẹrindinlogun osu Kọkanla ọdun yii, eyiun ọjọ Satide ọtunla.
Ileẹjọ salaye pe eto idibo abẹnu ti wọn ti yan oludije ninu ẹgbẹ APC ni Bayelsa ko ba ilana ati ofin ẹgbẹ oselu APC mu rara.
David Lyon ni oludije ẹgbẹ APC ti ibo abẹnu naa fa kalẹ, to si ti fidi rẹmi bayii nitori asẹ ileẹjọ yii, nigba ti ibo gomina ọhun ku ọjọ meji pere ko waye.
Senator Douye Diri ni alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu PDP.
Nígbà to n gbé ìdaájọ náà kalẹ adájọ Jane Inyang, sàlàyé pé ẹjọ ti Sẹnatọ Heineken Lokpobiri pe, fí hàn pé ìlànà tí wọ́n fi ṣe ìdìbò àbẹ́lé to gbé David Lyon wọle, ní ọjọ kẹrin oṣu kẹsan kò ba òfin ẹgbẹ́ mu.
Nítori náà, adajọ Inyang pàsẹ pe ki àjọ eletò idìbò yọ orúkọ olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Lyon kúro, nínú àwọn oludije ibo gomina ti yóò dije lọ́jọ́ Sátide ọsẹ̀ yìí.
Inyang ni gẹ́gẹ́ bi ilana ofin ẹgbẹ oselu APC feto idibo abẹnu fawọn oludije gomina lọdun 2019, alabojuto ibo náà, tii tun se Gomina Ipinlẹ Yobe, Kala Buni lo yẹ ko kede esi ibo ati ẹni to jawe olubori, kìí ṣe sẹnatọ Emmanuel Ochega, to jẹ akọwe ìgbìmọ to se kokari idibo abẹnu ọhun.
O tún fi kún pé, APC tẹ ofin ara rẹ̀ lóju mọ́lẹ̀ pẹlu bó ṣe yàn ìgbìmọ̀ ẹlẹni kan dípò igbimọ ẹlẹni méje ti òfin ẹgbẹ́ sọ.
"Eyí ti fidí múlẹ̀ lati ọ̀dọ̀ àwọn alásẹ nibi idájọ àti ọ̀pọ̀ àwọn ìdájọ míràn pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú gbọdọ dúró lóri òfin ti wọ́n là sílẹ̀, Awọn ìgbìmọ to ságbátẹru ìdìbò abẹ́lé fi ìwà àìbíkìtà wọ́n sọ olúdijé náà si ipò to wà