Lagos Housing: 'Àwọn ayálégbé máa san mílíọ̀nú mẹ́rin fún ilé oníyàrá méjì lágbègbè V.I. l'Eko '

Wiwa ilegbe jẹ ọkan lara ipenija tawọn ọdọ n doju kọ, ṣugbọn ti ilu Eko tun le kenka.

Ọpọ onile ni wọn maa n beere fun owo agbaalẹ lọwọ awọn ayalegbe ki wọn to le gba wọn sile.

Awọn onile maa n gbe ile to ni yara meji lagbegbe Victoria Island silẹ fun miliọnu mẹrin naira, tawọn mii si maa gba miliọnu mẹjọ ni agbaalẹ.

Fun ọpọ oṣiṣẹ niluu Eko, owo ile bẹrẹ lati bi miliọnu meji si miliọnu mejidinlogun lọdun kan.

Ohun kan tawọn onile maa n sọ pe o jẹ ki owo ile wọn ni pe owo ilẹ ati ohun eroja ikọle pọ ju.

Awọn onile ni sisan owo silẹ pe ju niluu Eko, ko pe awọn ti wọn ba ṣẹṣẹ ri iṣẹ.

Ọgbẹni Bankole Oluwafemi to n ṣiṣẹ ara rẹ gba ile si agbegbe Lekki nibi tawọn to rọwọ họri diẹ n gbe.

Lori ayelujara ni Ọgbẹni Oluwafemi ti ri ile ọhun ko to sanwo rẹ.

Bo tilẹ jẹ wi pe ijọba ṣofin lọdun 2011 pe kawọn onile ma gba ju owo ọdun kan lọ mọ, ofin naa ko fi bẹẹ mulẹ to.

Ọgbẹni Dolapo Olumidire to jẹ onwoye nipa ọrọ ilẹ sọ pe ilu Eko da bi ọja fun awọn onile.

Aye nira fawọn eeyan to n gbe aarin meji erukusu ilu Eko sibi iyangbẹ ilẹ.

Wọn ni lati ji larọ kutu bi aago mẹrin lati wa okada ti yoo gbe wọn lọ si idikọ.